Hos 9:1-16

Hos 9:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

MÁṢE yọ̀, Israeli, fun ayọ̀, bi awọn enia miràn: nitori iwọ ti ṣe agbère lọ kuro lọdọ Ọlọrun rẹ, iwọ ti fẹ́ èrè lori ilẹ ipakà gbogbo. Ilẹ ipakà ati ohun ifunti kì yio bọ́ wọn, ọti-waini titun yio si tan ninu rẹ̀. Nwọn kì yio gbe inu ilẹ Oluwa; ṣugbọn Efraimu yio padà si Egipti, nwọn o si jẹ ohun aimọ́ ni Assiria. Nwọn kì yio ta Oluwa li ọrẹ ọti-waini, bẹ̃ni nwọn kì yio mu u ni inu dùn: ẹbọ wọn yio ri fun wọn bi onjẹ awọn ti nṣọ̀fọ; gbogbo awọn ti o jẹ ninu rẹ̀ ni yio di alaimọ́: nitori onjẹ wọn kì yio wá si ile Oluwa fun ọkàn wọn. Kili ẹnyin o ṣe li ọjọ ti o ni irònu, ati li ọjọ àse Oluwa? Nitori, sa wò o, nwọn ti lọ nitori ikogun: Egipti yio kó wọn jọ, Memfisi yio sin wọn: ibi didara fun fadakà wọn li ẹgún-ọ̀gan yio jogun wọn: ẹgún yio wà ninu agọ wọn. Ọjọ ibẹ̀wo de, ọjọ ẹsan de; Israeli yio mọ̀: aṣiwère ni woli na, ẹni ẹmi na nsinwin; nitori ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ rẹ, ati irira nla na. Olùṣọ Efraimu wà pẹlu Ọlọrun mi: ṣugbọn okùn pẹyẹpẹyẹ ni woli na li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, ati irira si ile Ọlọrun rẹ̀. Nwọn ti ba ara wọn jẹ pupọ̀pupọ̀, bi li ọjọ Gibea: nitorina, on o ranti aiṣedẽde wọn, yio bẹ̀ ẹ̀ṣẹ wọn wò. Mo ri Israeli bi eso ajara li aginjù; mo ri awọn baba nyin bi akọpọ́n ninu igi ọpọ̀tọ li akọso rẹ̀: ṣugbọn nwọn tọ̀ Baal-peori lọ, nwọn si yà ara wọn si itiju nì; ohun irira wọn si ri gẹgẹ bi nwọn ti fẹ. Bi o ṣe ti Efraimu, ogo wọn yio fò lọ bi ẹiyẹ, lati ibí, ati lati inu, ati lati iloyun. Bi nwọn tilẹ tọ́ ọmọ wọn dàgba, ṣugbọn emi o gbà wọn li ọwọ wọn, ti kì yio fi kù enia kan; lõtọ, egbe ni fun wọn pẹlu nigbati mo ba kuro lọdọ wọn! Efraimu, bi mo ti ri Tirusi, li a gbìn si ibi daradara: ṣugbọn Efraimu yio bi ọmọ rẹ̀ fun apania. Fun wọn, Oluwa, li ohun ti iwọ o fun wọn. Fun wọn ni iṣẹnu ati ọmú gbigbẹ́. Gbogbo ìwa-buburu wọn mbẹ ni Gilgali; nitori nibẹ̀ ni mo korira wọn; nitori ìwa-buburu iṣe wọn, emi o le wọn kuro ni ile mi, emi kì yio fẹràn wọn mọ́; gbogbo ọmọ-alade wọn ni ọlọ̀tẹ. A lù Efraimu, gbòngbo wọn gbẹ, nwọn kì yio so eso, bi nwọn tilẹ bi ọmọ, ṣugbọn emi o pa ãyò eso inu wọn.

Hos 9:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ẹ má yọ̀, ẹ sì má dá ara yín ninu dùn, bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, nítorí ẹ ti kọ Ọlọrun yín sílẹ̀, ẹ ti ṣe àgbèrè ẹ̀sìn lọ sọ́dọ̀ oriṣa. Inú yín ń dùn sí owó iṣẹ́ àgbèrè ní gbogbo ibi ìpakà yín. Ọkà ibi ìpakà yín ati ọtí ibi ìpọntí yín kò ní to yín, kò sì ní sí waini tuntun mọ́. Àwọn ọmọ Israẹli kò ní dúró ní ilẹ̀ OLUWA mọ́; Efuraimu yóo pada sí Ijipti, wọn yóo sì jẹ ohun àìmọ́ ní ilẹ̀ Asiria. Wọn kò ní rú ẹbọ ohun mímu sí OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni ẹbọ wọn kò ní tẹ́ ẹ lọ́rùn. Oúnjẹ wọn yóo dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, àwọn tí wọ́n bá jẹ ninu rẹ̀ yóo di aláìmọ́. Ebi nìkan ni oúnjẹ wọn yóo wà fún, wọn kò ní mú wá fi rúbọ lára rẹ̀ ní ilé OLUWA. Kí ni wọn óo ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, kí ni wọn óo ṣe ní ọjọ́ àsè OLUWA? Wọn yóo fọ́nká lọ sí Asiria; Ijipti ni yóo gbá wọn jọ, Memfisi ni wọn yóo sin wọ́n sí, Ẹ̀gún ọ̀gàn ni yóo hù bo àwọn nǹkan èlò fadaka olówó iyebíye wọn, ẹ̀gún yóo sì hù ninu àgọ́ wọn. Àkókò ìjìyà ati ẹ̀san ti dé, Israẹli yóo sì mọ̀. Ẹ̀ ń wí pé, “Òmùgọ̀ ni wolii, aṣiwèrè sì ni ẹni tí ó wà ninu ẹ̀mí,” nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yín, ati ìkórìíra yín tí ó pọ̀. Wolii ni aṣọ́nà fún Efuraimu, àwọn eniyan Ọlọrun mi, sibẹsibẹ tàkúté àwọn pẹyẹpẹyẹ wà lójú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, ìkórìíra sì wà ní ilé Ọlọrun rẹ̀. Wọ́n ti sọ ara wọn di aláìmọ́ lọpọlọpọ, bí ìgbà tí wọ́n wà ní Gibea. Ọlọrun yóo ranti àìdára tí wọ́n ṣe, yóo sì jẹ wọ́n níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. OLUWA wí pé: “Mo rí Israẹli he bí ìgbà tí eniyan rí èso àjàrà he ninu aṣálẹ̀. Lójú mi, àwọn baba ńlá yín dàbí èso tí igi ọ̀pọ̀tọ́ kọ́ so ní àkókò àkọ́so rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rí sí mi, ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé òkè Baali Peori, wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ fún oriṣa Baali, wọ́n sì di ohun ẹ̀gbin, bí oriṣa tí wọ́n fẹ́ràn. Ògo Efuraimu yóo fò lọ bí ẹyẹ, wọn kò ní lóyún, wọn kò ní bímọ, bẹ́ẹ̀ ni ọlẹ̀ kò ní sọ ninu wọn! Bí wọ́n bá tilẹ̀ bímọ, n óo pa wọ́n tí kò ní ku ẹyọ kan. Bí mo bá kọ̀ wọ́n sílẹ̀, wọ́n gbé!” Mo rí àwọn ọmọ Efuraimu bí ẹran àpajẹ; Efuraimu gbọdọ̀ kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún pípa. Fún wọn ní nǹkankan, OLUWA, OLUWA, kí ni ò bá tilẹ̀ fún wọn? Jẹ́ kí oyún máa bàjẹ́ lára obinrin wọn, kí ọmú wọn sì gbẹ. OLUWA ní, “Gbogbo ìwà burúkú wọn wà ní Giligali, ibẹ̀ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra wọn. Nítorí iṣẹ́ burúkú wọn, n óo lé wọn jáde ní ilé mi. N kò ní fẹ́ràn wọn mọ́, ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo àwọn olórí wọn. Ìyà jẹ Efuraimu, gbòǹgbò wọn ti gbẹ, wọn kò sì ní so èso mọ́. Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ, n óo pa àwọn ọmọ tí wọ́n fẹ́ràn.”

Hos 9:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Má ṣe yọ̀, ìwọ Israẹli; má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìṣòótọ́ si Ọlọ́run yín. Ẹ fẹ́ràn láti gba owó iṣẹ́ àgbèrè ní gbogbo ilẹ̀ ìpakà. Àwọn ilẹ̀ ìpakà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀ Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé OLúWA Efraimu yóò padà sí Ejibiti Yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ́ ní Asiria. Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún OLúWA. Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn. Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀. Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́. Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnrawọn kò ní wá sí orí tẹmpili OLúWA. Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún OLúWA? Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun Ejibiti yóò kó wọn jọ, Memfisi yóò sì sin wọ́n. Ibi ìsọjọ̀ fàdákà wọn ni ẹ̀gún yóò jogún, Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn. Ẹ̀gún yóò sì bo gbogbo àgọ́ wọn. Àwọn ọjọ́ ìjìyà ń bọ̀; àwọn ọjọ́ ìṣirò iṣẹ́ ti dé Jẹ́ kí Israẹli mọ èyí Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ ìkórìíra yín sì pọ̀ gan an ni. A ka àwọn wòlíì sí òmùgọ̀ A ka ẹni ìmísí sí asínwín. Wòlíì, papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ni olùṣọ́ ọ Efraimu. Síbẹ̀ ìdẹ̀kùn dúró dè é ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti ìkórìíra ní ilé Ọlọ́run rẹ̀ Wọ́n ti gbilẹ̀ nínú ìwà ìbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ Gibeah Ọlọ́run yóò rántí ìwà búburú wọn yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. “Mo rí Israẹli bí èso àjàrà ní aginjù. Mo rí àwọn baba yín, bí àkọ́pọ́n nínú igi ọ̀pọ̀tọ́ ní àkọ́so rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n tọ Baali-Peori lọ, wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni, ohun ìríra wọn sì rí gẹ́gẹ́ bí wọn ti fẹ́. Ògo Efraimu yóò fò lọ bí ẹyẹ kò ní sí ìfẹ́rakù, ìlóyún àti ìbímọ. Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà. Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn Ègbé ni fún wọn, nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn! Mo rí Efraimu bí ìlú Tire tí a tẹ̀dó sí ibi dáradára ṣùgbọ́n Efraimu yóò kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn.” Fún wọn, OLúWA! Kí ni ìwọ yóò fún wọn? Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́ àti ọyàn gbígbẹ. “Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gilgali Mo kórìíra wọn níbẹ̀, nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́ ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn. Efraimu ti rẹ̀ dànù gbogbo rẹ̀ sì ti rọ, kò sì so èso, Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ. Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.”