Hos 11:1-11

Hos 11:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBATI Israeli wà li ọmọde, nigbana ni mo fẹ́ ẹ, mo si pè ọmọ mi lati Egipti jade wá. Bi nwọn ti pè wọn, bẹ̃ni nwọn lọ kuro lọdọ wọn: nwọn rubọ si Baalimu, nwọn si fi turari joná si ere fifin. Mo kọ́ Efraimu pẹlu lati rìn, mo dì wọn mu li apa, ṣugbọn nwọn kò mọ̀ pe mo ti mu wọn lara dá. Mo fi okùn enia fà wọn, ati idè ifẹ: mo si ri si wọn bi awọn ti o mu ajàga kuro li ẹrẹkẹ wọn, mo si gbe onjẹ kalẹ niwaju wọn. On kì yio yipadà si ilẹ Egipti, ṣugbọn ara Assiria ni yio jẹ ọba rẹ̀, nitori nwọn kọ̀ lati yipadà. Idà yio si ma gbe inu ilu rẹ̀, yio si run ìtikun rẹ̀, yio si jẹ wọn run, nitori ìmọran ara wọn. Awọn enia mi si tẹ̀ si ifàsẹhin kuro lọdọ mi: bi o tilẹ̀ ṣepe nwọn pè wọn si Ọga-ogo jùlọ, nwọn kò jùmọ gbe e ga. Emi o ha ṣe jọwọ rẹ lọwọ, Efraimu? emi o ha ṣe gbà ọ silẹ, Israeli? emi o ha ti ṣe ṣe ọ bi Adma? emi o ha ti ṣe gbe ọ kalẹ bi Seboimu, ọkàn mi yi ninu mi, iyọnu mi gbiná pọ̀. Emi kì yio mu gbigboná ibinu mi ṣẹ, emi kì yio yipadà lati run Efraimu: nitori Ọlọrun li emi, kì iṣe enia; Ẹni-Mimọ lãrin rẹ: emi kì yio si wá ninu ibinu. Nwọn o ma tẹ̀le Oluwa: on o ke ramùramù bi kiniun: nigbati on o ke, nigbana li awọn ọmọ yio wariri lati iwọ-õrun wá. Nwọn o warìri bi ẹiyẹ lati Egipti wá, ati bi adàba lati ilẹ Assiria wá: emi o si fi wọn si ile wọn, li Oluwa wi.

Hos 11:1-11 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní, “Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọde, mo fẹ́ràn rẹ̀, láti ilẹ̀ Ijipti ni mo sì ti pe ọmọ mi jáde. Ṣugbọn bí mo ti ń pè wọ́n tó, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń sá fún mi, wọ́n ń rúbọ sí àwọn oriṣa Baali, wọ́n ń sun turari sí ère. Bẹ́ẹ̀ ni èmi ni mo kọ́ Efuraimu ní ìrìn, mo gbé wọn lé ọwọ́ mi, ṣugbọn wọn kò mọ̀ pé èmi ni mo wo àwọn sàn. Mo fà wọ́n mọ́ra pẹlu okùn àánú ati ìdè ìfẹ́, mo dàbí ẹni tí ó tú àjàgà kúrò ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn, mo sì bẹ̀rẹ̀, mo gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn. “Wọn óo pada sí ilẹ̀ Ijipti, Asiria óo sì jọba lé wọn lórí, nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi. A óo fi idà run àwọn ìlú wọn, irin ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè wọn yóo ṣẹ́, a óo sì pa wọ́n run ninu ibi ààbò wọn. Àwọn eniyan mi ti pinnu láti yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí náà n óo ti àjàgà bọ̀ wọ́n lọ́rùn, kò sì ní sí ẹni tí yóo bá wọn bọ́ ọ. “Mo ha gbọdọ̀ yọwọ́ lọ́rọ̀ yín ẹ̀yin Efuraimu? Mo ha gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, Israẹli? Mo ha gbọdọ̀ pa ọ́ run bí mo ti pa Adimai run; kí n ṣe sí ọ bí mo ti ṣe sí Seboimu? Ọkàn mi kò gbà á, àánú yín a máa ṣe mí. N kò ní fa ibinu yọ mọ́, n kò ní pa Efuraimu run mọ́, nítorí pé Ọlọrun ni mí, n kì í ṣe eniyan, èmi ni Ẹni Mímọ́ tí ó wà láàrin yín, n kò sì ní pa yín run. “Àwọn ọmọ Israẹli yóo wá mi, n óo sì bú bíi kinniun; lóòótọ́ n óo bú, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin yóo sì fi ìbẹ̀rùbojo jáde wá láti ìwọ̀ oòrùn; wọn yóo fi ìbẹ̀rùbojo fò wá bí ẹyẹ láti ilẹ̀ Ijipti, ati bí ẹyẹ àdàbà láti ilẹ̀ Asiria; n óo sì dá wọn pada sí ilé wọn. Èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀.”

Hos 11:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀, mo sì pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá. Bí a ti ń pe wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn rú ẹbọ sí Baali, wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín. Lóòtítọ́ mo kọ́ Efraimu pẹ̀lú ní ìrìn mo di wọ́n mú ní apá, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo ti mú wọn láradá. Mo fi okùn ènìyàn fà wọ́n àti ìdè ìfẹ́. Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn Mo sì fi ara balẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ. “Ṣé wọn ò wá ní padà sí Ejibiti bí Ṣé Asiria kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronúpìwàdà? Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọn yóò si bá gbogbo irin ẹnu odi ìlú wọn jẹ́ yóò sì fi òpin sí gbogbo èrò wọn. Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ Ọ̀gá-ògo jùlọ, kò ní gbé wọn ga rárá. “Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Efraimu? Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Israẹli Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Adma? Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ṣeboimu? Ọkàn mi yípadà nínú mi àánú mi sì ru sókè Èmi kò ni mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ, tàbí kí èmi wá sọ Efraimu di ahoro. Nítorí pé èmi ni Ọlọ́run, àní, èmi kì í ṣe ènìyàn Ẹni mímọ́ láàrín yín, Èmi kò ní í wá nínú ìbínú Wọn yóò máa tẹ̀lé OLúWA; òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìún Nígbà tó bá bú àwọn ọmọ rẹ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀-oòrùn. Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rù bí i ẹyẹ láti Ejibiti bí i àdàbà láti Asiria Èmi ó mú wọn padà sí ilé wọn,” ni OLúWA wí.