HOSIA 11
11
Ìfẹ́ Ọlọrun sí Àwọn Eniyan Rẹ̀, Ọlọ̀tẹ̀
1OLUWA ní,
“Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọde, mo fẹ́ràn rẹ̀,
láti ilẹ̀ Ijipti ni mo sì ti pe ọmọ mi jáde.#Eks 4:22; Mat 2:15
2Ṣugbọn bí mo ti ń pè wọ́n tó,
bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń sá fún mi,
wọ́n ń rúbọ sí àwọn oriṣa Baali,
wọ́n ń sun turari sí ère.
3Bẹ́ẹ̀ ni èmi ni mo kọ́ Efuraimu ní ìrìn,
mo gbé wọn lé ọwọ́ mi,
ṣugbọn wọn kò mọ̀ pé èmi ni mo wo àwọn sàn.
4Mo fà wọ́n mọ́ra pẹlu okùn àánú ati ìdè ìfẹ́,
mo dàbí ẹni tí ó tú àjàgà kúrò ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn,
mo sì bẹ̀rẹ̀, mo gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn.
5“Wọn óo pada sí ilẹ̀ Ijipti, Asiria óo sì jọba lé wọn lórí, nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi. 6A óo fi idà run àwọn ìlú wọn, irin ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè wọn yóo ṣẹ́, a óo sì pa wọ́n run ninu ibi ààbò wọn. 7Àwọn eniyan mi ti pinnu láti yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí náà n óo ti àjàgà bọ̀ wọ́n lọ́rùn, kò sì ní sí ẹni tí yóo bá wọn bọ́ ọ.
8“Mo ha gbọdọ̀ yọwọ́ lọ́rọ̀ yín ẹ̀yin Efuraimu?
Mo ha gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, Israẹli?
Mo ha gbọdọ̀ pa ọ́ run bí mo ti pa Adimai run;
kí n ṣe sí ọ bí mo ti ṣe sí Seboimu?
Ọkàn mi kò gbà á,
àánú yín a máa ṣe mí.#Diut 29:23
9N kò ní fa ibinu yọ mọ́,
n kò ní pa Efuraimu run mọ́,
nítorí pé Ọlọrun ni mí,
n kì í ṣe eniyan,
èmi ni Ẹni Mímọ́ tí ó wà láàrin yín,
n kò sì ní pa yín run.
10“Àwọn ọmọ Israẹli yóo wá mi, n óo sì bú bíi kinniun; lóòótọ́ n óo bú, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin yóo sì fi ìbẹ̀rùbojo jáde wá láti ìwọ̀ oòrùn; 11wọn yóo fi ìbẹ̀rùbojo fò wá bí ẹyẹ láti ilẹ̀ Ijipti, ati bí ẹyẹ àdàbà láti ilẹ̀ Asiria; n óo sì dá wọn pada sí ilé wọn. Èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀.”
Ìdájọ́ lórí Juda ati Israẹli
12OLUWA ní, “Àwọn ọmọ Efuraimu parọ́ fún mi, ilẹ̀ Israẹli kún fún ẹ̀tàn, sibẹsibẹ mo mọ ilé Juda, nítorí pé ó jẹ́ olóòótọ́ sí èmi, Ẹni Mímọ́.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
HOSIA 11: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010