Hosea 11:1-11

Hosea 11:1-11 YCB

“Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀, mo sì pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá. Bí a ti ń pe wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn rú ẹbọ sí Baali, wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín. Lóòtítọ́ mo kọ́ Efraimu pẹ̀lú ní ìrìn mo di wọ́n mú ní apá, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo ti mú wọn láradá. Mo fi okùn ènìyàn fà wọ́n àti ìdè ìfẹ́. Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn Mo sì fi ara balẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ. “Ṣé wọn ò wá ní padà sí Ejibiti bí Ṣé Asiria kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronúpìwàdà? Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọn yóò si bá gbogbo irin ẹnu odi ìlú wọn jẹ́ yóò sì fi òpin sí gbogbo èrò wọn. Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ Ọ̀gá-ògo jùlọ, kò ní gbé wọn ga rárá. “Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Efraimu? Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Israẹli Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Adma? Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ṣeboimu? Ọkàn mi yípadà nínú mi àánú mi sì ru sókè Èmi kò ni mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ, tàbí kí èmi wá sọ Efraimu di ahoro. Nítorí pé èmi ni Ọlọ́run, àní, èmi kì í ṣe ènìyàn Ẹni mímọ́ láàrín yín, Èmi kò ní í wá nínú ìbínú Wọn yóò máa tẹ̀lé OLúWA; òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìún Nígbà tó bá bú àwọn ọmọ rẹ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀-oòrùn. Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rù bí i ẹyẹ láti Ejibiti bí i àdàbà láti Asiria Èmi ó mú wọn padà sí ilé wọn,” ni OLúWA wí.