Esek 43:1-17

Esek 43:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na, ẹnu-ọ̀na ti o kọjusi ọ̀na ila-õrun: Si kiyesi i, ogo Ọlọrun Israeli wá lati ọ̀na ila-õrun: ati ohùn rẹ̀ ri bi ariwo omi pupọ̀: aiye si ràn fun ogo rẹ̀. O si dabi irí iran ti mo ri, gẹgẹ bi iran ti mo ri nigbati mo wá lati pa ilu na run: iran na si dabi iran ti mo ri lẹba odò Kebari, mo si doju mi bolẹ. Ogo Oluwa si wá si ile na lati ọ̀na ilẹkùn ti o kọjusi ọ̀na ila-õrun. Ẹmi si gbe mi soke, o si mu mi wá si àgbala tinu: si kiye si i, ogo Oluwa kún ile na. Mo si gbọ́ o mba mi sọ̀rọ lati inu ile wá; ọkunrin na si duro tì mi. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, ibi itẹ mi, ati ibi atẹlẹṣẹ mi, nibiti emi o gbe lãrin awọn ọmọ Israeli lailai, ati orukọ mimọ́ mi, ni ki ile Israeli má bajẹ mọ, awọn, tabi ọba wọn, nipa panṣaga wọn, tabi nipa okú ọba wọn ni ibi giga wọn. Ni titẹ́ iloro wọn nibi iloro mi, ati opó wọn nibi opó mi, ogiri si wà lãrin emi ati awọn, nwọn si ti ba orukọ mimọ́ mi jẹ nipa ohun irira wọn ti nwọn ti ṣe: mo si run wọn ni ibinu mi. Njẹ ki nwọn mu panṣaga wọn, ati okú awọn ọba wọn jina kuro lọdọ mi, emi o si ma gbe ãrin wọn lailai. Iwọ ọmọ enia, fi ile na hàn ile Israeli, ki oju aiṣedede wọn ba le tì wọn: si jẹ ki nwọn wọ̀n apẹrẹ na. Bi oju gbogbo ohun ti nwọn ba ṣe ba si tì wọn, fi irí ile na hàn wọn, ati kikọ́ rẹ̀, ati ijade rẹ̀, ati iwọle rẹ̀, ati gbogbo irí rẹ̀, ati gbogbo aṣẹ rẹ̀, ati gbogbo irí rẹ̀, ati gbogbo ofin rẹ̀; ki o si kọ ọ loju wọn, ki nwọn ki o lè pa gbogbo irí rẹ̀ mọ, ati gbogbo aṣẹ rẹ̀, ki nwọn si ṣe wọn. Eyi ni ofin ile na; Lori oke giga, gbogbo ipinnu rẹ̀ yika ni mimọ́ julọ. Kiyesi i, eyi ni ofin ile na. Wọnyi si ni iwọ̀n pẹpẹ nipa igbọnwọ; Igbọnwọ jẹ igbọnwọ kan ati ibú atẹlẹwọ kan; isalẹ rẹ̀ yio jẹ igbọnwọ kan, ati ibu rẹ̀ igbọnwọ kan, ati igbati rẹ̀ ni eti rẹ̀ yika yio jẹ ika kan: eyi ni yio si jẹ ibi giga pẹpẹ na. Lati isalẹ ilẹ titi de ijoko isalẹ yio jẹ igbọnwọ meji, ati ibú rẹ̀ igbọnwọ́ kan; ati lati ijoko kekere titi de ijoko nla yio jẹ igbọnwọ mẹrin, ati ibú rẹ̀ igbọnwọ kan. Pẹpẹ na si jẹ igbọnwọ mẹrin: ati lati pẹpẹ titi de oke jẹ iwo mẹrin. Pẹpẹ na yio si jẹ igbọnwọ mejila ni gigùn, ati mejila ni ibú onigun mẹrin ni igun mẹrẹrin rẹ̀. Ati ijoko ni yio jẹ igbọ̀nwọ mẹrinla ni gigun ati mẹrinla ni ibú ninu igun mẹrẹrin rẹ̀; ati eti rẹ̀ yika yio jẹ́ abọ̀ igbọnwọ; ati isalẹ rẹ̀ yio jẹ igbọnwọ kan yika; atẹgùn rẹ̀ yio si kọjusi iha ila-õrun.

Esek 43:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà, ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn. Wò ó! Ìtànṣán ògo Ọlọrun Israẹli yọ láti apá ìlà oòrùn, ìró bíbọ̀ rẹ̀ dàbí ti omi òkun, ìmọ́lẹ̀ ògo rẹ̀ sì tàn sórí ilẹ̀. Ìran tí mo rí yìí dàbí èyí tí mo rí nígbà tí Ọlọrun wá pa ìlú Jerusalẹmu run ati bí ìran tí mo rí létí odò Kebari; mo bá dojúbolẹ̀. Ìtànṣán ògo OLUWA wọ inú Tẹmpili láti ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. Ẹ̀mí bá gbé mi dìde, ó mú mi wá sinu gbọ̀ngàn inú; ìtànṣán ògo OLUWA sì kún inú Tẹmpili náà. Bí ọkunrin náà ti dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, mo gbọ́ tí ẹnìkan ń bá mi sọ̀rọ̀ láti inú Tẹmpili, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, ààyè ìtẹ́ mi nìyí, ati ibi ìgbẹ́sẹ̀lé mi. Níbẹ̀ ni n óo máa gbé láàrin àwọn eniyan Israẹli títí lae. Ilé Israẹli tabi àwọn ọba wọn kò ní fi àgbèrè ẹ̀sìn wọn, ati òkú àwọn ọba wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́. Wọn kò ní tẹ́ pẹpẹ wọn sí ẹ̀gbẹ́ tèmi mọ́, tabi kí wọn gbé òpó ìlẹ̀kùn wọn sí ẹ̀gbẹ́ tèmi; tí ó fi jẹ́ pé ògiri kan ni yóo wà láàrin èmi pẹlu wọn. Wọ́n ti fi ìwà ìríra wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́, nítorí náà ni mo ṣe fi ibinu pa wọ́n run. Kí wọ́n pa ìwà ìbọ̀rìṣà wọn tì, kí wọ́n sì gbé òkú àwọn ọba wọn jìnnà sí mi, n óo sì máa gbé ààrin wọn títí lae. “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣe àpèjúwe Tẹmpili yìí, sọ bí ó ti rí ati àwòrán kíkọ́ rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí ojú ẹ̀ṣẹ̀ wọn lè tì wọ́n. Bí ojú ohun tí wọ́n ṣe bá tì wọ́n, ṣe àlàyé Tẹmpili náà, bí o ti rí i, ẹnu ọ̀nà àbájáde ati àbáwọlé rẹ̀. Sọ bí o ti rí i fún wọn, sì fi àwọn àṣẹ ati òfin rẹ̀ hàn wọ́n. Kọ wọ́n sílẹ̀ lójú wọn, kí wọ́n lè máa pa àwọn àṣẹ ati òfin rẹ̀ mọ́. Òfin Tẹmpili nìyí, gbogbo agbègbè tí ó yí orí òkè ńlá tí ó wà ká gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ jùlọ.” Bí ìwọ̀n pẹpẹ náà ti rí nìyí; irú ọ̀pá kan náà tí ó jẹ́ igbọnwọ kan ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ (ìdajì mita kan) kan ni ó fi wọ̀n ọ́n. Pèpéle pẹpẹ náà yóo ga ní igbọnwọ kan, yóo fẹ̀ ní igbọnwọ kan. Etí rẹ̀ yíká fẹ̀ ní ìka kan (idamẹrin mita kan). Gíga pẹpẹ láti pèpéle tí ó wà nílẹ̀ títí dé ìtẹ́lẹ̀ ìsàlẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji (mita kan). Ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan (ìdajì mita kan). Láti ìtẹ́lẹ̀ kékeré títí dé ìtẹ́lẹ̀ ńlá jẹ́ igbọnwọ mẹrin (mita meji). Ibú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan (idaji mita kan). Orí pẹpẹ náà ga ní igbọnwọ mẹrin (mita meji). Ìwo mẹrin wà lára rẹ̀, wọ́n gùn ní igbọnwọ kọ̀ọ̀kan (ìdajì mita kan). Orí pẹpẹ náà ní igun mẹrin, òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mejila (mita mẹfa) ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila (mita mẹfa). Ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ náà ní igun mẹrin, ó ga ní igbọnwọ mẹrinla (mita meje), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrinla (mita meje). Etí rẹ̀ yíká jẹ́ ìdajì igbọnwọ (idamẹrin mita), pèpéle rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan yíká (ìdajì mita kan). Àtẹ̀gùn pẹpẹ náà kọjú sí apá ìlà oòrùn.

Esek 43:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi gba ti ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn, mo sì ri ògo Ọlọ́run Israẹli ń bọ láti ìhà ìlà-oòrùn. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi, ìtànṣán ògo rẹ̀ sì bo ilẹ̀. Ó sì dàbí ìran tí mo rí, gẹ́gẹ́ bí ìran tí mo rí nígbà tí mo wá láti pa ìlú náà run; ìran náà sì dà bí ìran tí mo rí lẹ́bàá odò Kebari, mo sì dojú mi bolẹ̀. Ògo OLúWA gba ọ̀nà tí o dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn wọ inú ilé Ọlọ́run wá. Mo ni ìrusókè ẹ̀mí, ó sì mú mi lọ inú ilé ìdájọ́, sì kíyèsi ògo OLúWA kún inú ilé Ọlọ́run. Nígbà tí ọkùnrin náà dúró ní ẹ̀gbẹ́ mi, mo gbọ́ ẹnìkan tí ó bá mi sọ̀rọ̀ láti inú ilé Ọlọ́run. Ó sì wí pé: “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ibi ìgúnwà mi àti ibi tí ó wà fún àtẹ́lẹsẹ̀ mi, Ibi yìí ni èmi yóò máa gbé ní àárín àwọn ọmọ Israẹli títí láéláé. Ilé Israẹli kò ní ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́ láéláé àwọn tàbí àwọn ọba wọn nípa àgbèrè àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn ọba wọn ní ibi gíga. Nígbà tí wọ́n ba gbé ìloro ilé wọn kángun sí ìloro ilé mi àti ìlẹ̀kùn wọn sì ẹ̀gbẹ́ ìlẹ̀kùn mi, pẹ̀lú ògiri nìkan ní àárín èmi pẹ̀lú wọn, wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ìwà ìríra wọn. Nígbà náà ni mo pa wọ́n run ní ìbínú mi. Nísinsin yìí jẹ́ kí wọn mú ìwà àgbèrè wọn àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn ọba wọn kúrò ni iwájú mi, èmi yóò sì gbé àárín wọn láéláé. “Ọmọ ènìyàn, ṣàpèjúwe ilé Ọlọ́run náà fún àwọn ènìyàn Israẹli kí ojú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, lè tì wọ́n sì jẹ́ kí wọn wo àwòrán ilé náà, tí ojú gbogbo ohun tí wọn ti ṣe bá tì wọ́n, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ àwòrán ilé Ọlọ́run náà bí wọ́n ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ, àbájáde àti àbáwọlé rẹ̀ gbogbo àwòrán àti gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀. Kọ ìwọ̀nyí sílẹ̀ ní iwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ́ olóòtítọ́ si àwòrán rẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀. “Èyí yìí ní òfin ilé Ọlọ́run náà: Gbogbo àyíká lórí òkè gíga ní yóò jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ. Bí èyí ni òfin tẹmpili náà. “Ìwọ̀nyí ni wíwọ̀n pẹpẹ ìrúbọ ní gígùn ìgbọ̀nwọ́, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni jíjìn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni ìbú, igun rẹ̀ yípo àti etí rẹ̀ jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan: Èyí yìí sì ni gíga pẹpẹ ìrúbọ náà: Láti ìsàlẹ̀ rẹ̀ ni ilẹ̀ títí dé ìsàlẹ̀ igun rẹ̀, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga o sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ní ìbú: Ibi ìdáná pẹpẹ ìrúbọ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga, ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì yọrí jáde sókè láti ibi ìdáná. Ibi ìdáná pẹpẹ náà jẹ́ igun mẹ́rin mẹ́rin lọ́gbọọgba, ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní gígùn, o sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní ìbú. Igun ni apá òkè náà jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní ìbú, pẹ̀lú etí tí ó jẹ́ ìdajì ìgbọ̀nwọ́, ìsàlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan yípo. Àtẹ̀gùn pẹpẹ ìrúbọ náà dojúkọ ìlà-oòrùn.”