ISIKIẸLI 43

43
Ọlọrun Pada Sinu Tẹmpili
1Lẹ́yìn náà, ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn. 2Wò ó! Ìtànṣán ògo Ọlọrun Israẹli yọ láti apá ìlà oòrùn, ìró bíbọ̀ rẹ̀ dàbí ti omi òkun, ìmọ́lẹ̀ ògo rẹ̀ sì tàn sórí ilẹ̀. 3Ìran tí mo rí yìí dàbí èyí tí mo rí nígbà tí Ọlọrun wá pa ìlú Jerusalẹmu run ati bí ìran tí mo rí létí odò Kebari; mo bá dojúbolẹ̀. 4Ìtànṣán ògo OLUWA wọ inú Tẹmpili láti ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. #Isi 10:3-4, 18-19; 11:22-23; Ifi 1:15
5Ẹ̀mí bá gbé mi dìde, ó mú mi wá sinu gbọ̀ngàn inú; ìtànṣán ògo OLUWA sì kún inú Tẹmpili náà. 6Bí ọkunrin náà ti dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, mo gbọ́ tí ẹnìkan ń bá mi sọ̀rọ̀ láti inú Tẹmpili, ó ní: 7“Ìwọ ọmọ eniyan, ààyè ìtẹ́ mi nìyí, ati ibi ìgbẹ́sẹ̀lé mi. Níbẹ̀ ni n óo máa gbé láàrin àwọn eniyan Israẹli títí lae. Ilé Israẹli tabi àwọn ọba wọn kò ní fi àgbèrè ẹ̀sìn wọn, ati òkú àwọn ọba wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́. 8Wọn kò ní tẹ́ pẹpẹ wọn sí ẹ̀gbẹ́ tèmi mọ́, tabi kí wọn gbé òpó ìlẹ̀kùn wọn sí ẹ̀gbẹ́ tèmi; tí ó fi jẹ́ pé ògiri kan ni yóo wà láàrin èmi pẹlu wọn. Wọ́n ti fi ìwà ìríra wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́, nítorí náà ni mo ṣe fi ibinu pa wọ́n run. 9Kí wọ́n pa ìwà ìbọ̀rìṣà wọn tì, kí wọ́n sì gbé òkú àwọn ọba wọn jìnnà sí mi, n óo sì máa gbé ààrin wọn títí lae.
10“Ìwọ ọmọ eniyan, ṣe àpèjúwe Tẹmpili yìí, sọ bí ó ti rí ati àwòrán kíkọ́ rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí ojú ẹ̀ṣẹ̀ wọn lè tì wọ́n. 11Bí ojú ohun tí wọ́n ṣe bá tì wọ́n, ṣe àlàyé Tẹmpili náà, bí o ti rí i, ẹnu ọ̀nà àbájáde ati àbáwọlé rẹ̀. Sọ bí o ti rí i fún wọn, sì fi àwọn àṣẹ ati òfin rẹ̀ hàn wọ́n. Kọ wọ́n sílẹ̀ lójú wọn, kí wọ́n lè máa pa àwọn àṣẹ ati òfin rẹ̀ mọ́. 12Òfin Tẹmpili nìyí, gbogbo agbègbè tí ó yí orí òkè ńlá tí ó wà ká gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ jùlọ.”
Pẹpẹ
13Bí ìwọ̀n pẹpẹ náà ti rí nìyí; irú ọ̀pá kan náà tí ó jẹ́ igbọnwọ kan ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ (ìdajì mita kan) kan ni ó fi wọ̀n ọ́n. Pèpéle pẹpẹ náà yóo ga ní igbọnwọ kan, yóo fẹ̀ ní igbọnwọ kan. Etí rẹ̀ yíká fẹ̀ ní ìka kan (idamẹrin mita kan). 14Gíga pẹpẹ láti pèpéle tí ó wà nílẹ̀ títí dé ìtẹ́lẹ̀ ìsàlẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji (mita kan). Ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan (ìdajì mita kan). Láti ìtẹ́lẹ̀ kékeré títí dé ìtẹ́lẹ̀ ńlá jẹ́ igbọnwọ mẹrin (mita meji). Ibú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan (idaji mita kan). 15Orí pẹpẹ náà ga ní igbọnwọ mẹrin (mita meji). Ìwo mẹrin wà lára rẹ̀, wọ́n gùn ní igbọnwọ kọ̀ọ̀kan (ìdajì mita kan). 16Orí pẹpẹ náà ní igun mẹrin, òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mejila (mita mẹfa) ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila (mita mẹfa). 17Ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ náà ní igun mẹrin, ó ga ní igbọnwọ mẹrinla (mita meje), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrinla (mita meje). Etí rẹ̀ yíká jẹ́ ìdajì igbọnwọ (idamẹrin mita), pèpéle rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan yíká (ìdajì mita kan). Àtẹ̀gùn pẹpẹ náà kọjú sí apá ìlà oòrùn. #Eks 27:1-2; 2 Kro 4:1
Yíya Pẹpẹ Sí Mímọ́
18Ọkunrin náà wí fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Àwọn òfin pẹpẹ nìwọ̀nyí, ní ọjọ́ tí a bá gbé e kalẹ̀ láti máa rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ ati láti máa ta ẹ̀jẹ̀ sí i lára, 19ẹ óo fún àwọn alufaa, ọmọ Lefi, láti inú ìran Sadoku, tí wọn ń rú ẹbọ sí mi, ní akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. 20Ẹ óo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ óo fi sí ara ìwo pẹpẹ ati igun mẹrẹẹrin pèpéle rẹ̀, ati ara etí rẹ̀ yíká, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe wẹ pẹpẹ náà mọ́; bẹ́ẹ̀ ni ètò ìwẹ̀nùmọ́ pẹpẹ lọ. 21Ẹ óo mú akọ mààlúù ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; ẹ óo sun ún ní ibi tí a yàn lára ilẹ̀ Tẹmpili ní ìta ibi mímọ́. 22Ní ọjọ́ keji ẹ óo fi òbúkọ tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹ ya pẹpẹ náà sí mímọ́ bí ẹ ti fi ẹbọ akọ mààlúù yà á sí mímọ́. 23Bí ẹ bá ti yà á sí mímọ́ tán, ẹ óo mú akọ mààlúù tí kò ní àbààwọ́n ati àgbò tí kò ní àbààwọ́n láti inú agbo ẹran, ẹ óo fi rú ẹbọ. 24Ẹ óo kó wọn wá siwaju OLUWA, alufaa yóo wọ́n iyọ̀ lé wọn lórí, yóo sì fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA. 25Lojoojumọ, fún ọjọ́ meje, ẹ óo máa mú ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan ati akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n láti inú agbo ẹran, ẹ óo máa fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. 26Fún ọjọ́ meje ni ẹ óo fi máa rú ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ fún pẹpẹ náà tí ẹ óo sì máa yà á sí mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yà á sọ́tọ̀ fún lílò. 27Tí ètò àwọn ọjọ́ wọnyi bá ti parí, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹjọ, àwọn alufaa yóo máa rú ẹbọ sísun yín ati ẹbọ alaafia yín lórí pẹpẹ náà, n óo sì máa tẹ́wọ́gbà wọ́n. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ” #Eks 29:35-37; 1 Makab 4:52-56

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ISIKIẸLI 43: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀