Esek 43
43
1O si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na, ẹnu-ọ̀na ti o kọjusi ọ̀na ila-õrun:
2Si kiyesi i, ogo Ọlọrun Israeli wá lati ọ̀na ila-õrun: ati ohùn rẹ̀ ri bi ariwo omi pupọ̀: aiye si ràn fun ogo rẹ̀.
3O si dabi irí iran ti mo ri, gẹgẹ bi iran ti mo ri nigbati mo wá lati pa ilu na run: iran na si dabi iran ti mo ri lẹba odò Kebari, mo si doju mi bolẹ.
4Ogo Oluwa si wá si ile na lati ọ̀na ilẹkùn ti o kọjusi ọ̀na ila-õrun.
5Ẹmi si gbe mi soke, o si mu mi wá si àgbala tinu: si kiye si i, ogo Oluwa kún ile na.
6Mo si gbọ́ o mba mi sọ̀rọ lati inu ile wá; ọkunrin na si duro tì mi.
7O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, ibi itẹ mi, ati ibi atẹlẹṣẹ mi, nibiti emi o gbe lãrin awọn ọmọ Israeli lailai, ati orukọ mimọ́ mi, ni ki ile Israeli má bajẹ mọ, awọn, tabi ọba wọn, nipa panṣaga wọn, tabi nipa okú ọba wọn ni ibi giga wọn.
8Ni titẹ́ iloro wọn nibi iloro mi, ati opó wọn nibi opó mi, ogiri si wà lãrin emi ati awọn, nwọn si ti ba orukọ mimọ́ mi jẹ nipa ohun irira wọn ti nwọn ti ṣe: mo si run wọn ni ibinu mi.
9Njẹ ki nwọn mu panṣaga wọn, ati okú awọn ọba wọn jina kuro lọdọ mi, emi o si ma gbe ãrin wọn lailai.
10Iwọ ọmọ enia, fi ile na hàn ile Israeli, ki oju aiṣedede wọn ba le tì wọn: si jẹ ki nwọn wọ̀n apẹrẹ na.
11Bi oju gbogbo ohun ti nwọn ba ṣe ba si tì wọn, fi irí ile na hàn wọn, ati kikọ́ rẹ̀, ati ijade rẹ̀, ati iwọle rẹ̀, ati gbogbo irí rẹ̀, ati gbogbo aṣẹ rẹ̀, ati gbogbo irí rẹ̀, ati gbogbo ofin rẹ̀; ki o si kọ ọ loju wọn, ki nwọn ki o lè pa gbogbo irí rẹ̀ mọ, ati gbogbo aṣẹ rẹ̀, ki nwọn si ṣe wọn.
12Eyi ni ofin ile na; Lori oke giga, gbogbo ipinnu rẹ̀ yika ni mimọ́ julọ. Kiyesi i, eyi ni ofin ile na.
13Wọnyi si ni iwọ̀n pẹpẹ nipa igbọnwọ; Igbọnwọ jẹ igbọnwọ kan ati ibú atẹlẹwọ kan; isalẹ rẹ̀ yio jẹ igbọnwọ kan, ati ibu rẹ̀ igbọnwọ kan, ati igbati rẹ̀ ni eti rẹ̀ yika yio jẹ ika kan: eyi ni yio si jẹ ibi giga pẹpẹ na.
14Lati isalẹ ilẹ titi de ijoko isalẹ yio jẹ igbọnwọ meji, ati ibú rẹ̀ igbọnwọ́ kan; ati lati ijoko kekere titi de ijoko nla yio jẹ igbọnwọ mẹrin, ati ibú rẹ̀ igbọnwọ kan.
15Pẹpẹ na si jẹ igbọnwọ mẹrin: ati lati pẹpẹ titi de oke jẹ iwo mẹrin.
16Pẹpẹ na yio si jẹ igbọnwọ mejila ni gigùn, ati mejila ni ibú onigun mẹrin ni igun mẹrẹrin rẹ̀.
17Ati ijoko ni yio jẹ igbọ̀nwọ mẹrinla ni gigun ati mẹrinla ni ibú ninu igun mẹrẹrin rẹ̀; ati eti rẹ̀ yika yio jẹ́ abọ̀ igbọnwọ; ati isalẹ rẹ̀ yio jẹ igbọnwọ kan yika; atẹgùn rẹ̀ yio si kọjusi iha ila-õrun.
18O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Eyi ni aṣẹ pẹpẹ na li ọjọ ti nwọn o ṣe e, lati rú ọrẹ ẹbọ sisun lori rẹ̀, ati lati wọ́n ẹ̀jẹ sori rẹ̀.
19Iwọ o si fi ẹgbọrọ malu, fun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, fun awọn alufa, awọn Lefi, ti iṣe iru-ọmọ Sadoku, ti nsunmọ mi, lati ṣe iranṣẹ fun mi, ni Oluwa Ọlọrun wi.
20Iwọ o si mu ninu ẹjẹ rẹ̀, iwọ o si fi si iwo mẹrẹrin rẹ̀, ati si igun mẹrẹrin ijoko na, ati si eti rẹ̀ yika: iwọ o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ mọ́, iwọ o si ṣe etùtu rẹ̀.
21Iwọ o si mu ẹgbọrọ malu ti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, on o si sun u ni ibiti a yàn ni ile na lode ibi-mimọ́.
22Ati ni ọjọ keji iwọ o fi ọmọ ewurẹ alailabawọn rubọ ọrẹ ẹ̀ṣẹ; nwọn o si sọ pẹpẹ na di mimọ́, bi nwọn iti ifi ẹgbọrọ malu sọ ọ di mimọ́.
23Nigbati iwọ ba ti sọ ọ di mimọ tan, iwọ o fi ẹgbọrọ malu alailabawọn rubọ, ati àgbo alailabawọn lati inu agbo wá.
24Iwọ o si fi wọn rubọ niwaju Oluwa, awọn alufa yio si dà iyọ̀ si wọn, nwọn o si fi wọn rú ọrẹ ẹbọ sisun si Oluwa.
25Ọjọ meje ni iwọ o fi pèse obukọ fun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ lojojumọ: nwọn o si pèse ẹgbọrọ malu pẹlu ati àgbo lati inu agbo wá, ti nwọn ṣe ailabawọn.
26Ọjọ meje ni nwọn o fi wẹ̀ pẹpẹ, nwọn o si sọ ọ di mimọ́: nwọn o si yà ara wọn sọtọ̀.
27Nigbati ọjọ wọnyi ba pe, yio si ṣe, ni ọjọ kẹjọ, ati siwaju, awọn alufa yio ṣe ọrẹ ẹbọ sisun nyin lori pẹpẹ, ati ọrẹ ẹbọ idupẹ: emi o si gbà nyin, ni Oluwa Ọlọrun wi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Esek 43: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.