Eks 7:1-13

Eks 7:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si wi fun Mose pe, Wò o, emi fi ọ ṣe ọlọrun fun Farao: Aaroni arakunrin rẹ ni yio si ma ṣe wolĩ rẹ. Iwọ o sọ gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun ọ: Aaroni arakunrin rẹ ni yio si ma sọ fun Farao pe, ki o rán awọn ọmọ Israeli jade ni ilẹ rẹ̀. Emi o si mu Farao li àiya le, emi o si sọ iṣẹ-àmi mi ati iṣẹ-iyanu mi di pupọ̀ ni ilẹ Egipti. Ṣugbọn Farao ki yio gbọ́ ti nyin, emi o si fi ọwọ́ mi lé Egipti, emi o si fi idajọ nla mú awọn ogun mi, ani awọn ọmọ Israeli enia mi, jade kuro ni ilẹ Egipti. Awọn ara Egipti yio si mọ̀ pe, emi li OLUWA, nigbati mo ba nà ọwọ́ mi lé Egipti, ti mo si mú awọn ọmọ Israeli jade kuro lãrin wọn. Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃; bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn; bẹ̃ni nwọn ṣe. Mose jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún, Aaroni si jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún o le mẹta, nigbati nwọn sọ̀rọ fun Farao. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Nigbati Farao yio ba wi fun nyin pe, Ẹ fi iṣẹ-iyanu kan hàn: nigbana ni ki iwọ ki o wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si fi i lelẹ niwaju Farao, yio si di ejò. Mose ati Aaroni si wọle tọ̀ Farao lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn: Aaroni si fi ọpá rẹ̀ lelẹ niwaju Farao ati niwaju awọn iranṣẹ rẹ̀, o si di ejò. Nigbana ni Farao pẹlu pè awọn ọlọgbọ́n ati awọn oṣó: awọn pẹlu, ani awọn alalupayida Egipti, si fi idán wọn ṣe bẹ̃ gẹgẹ. Nitoriti olukuluku nwọn fi ọpá rẹ̀ lelẹ, nwọn si di ejò: ṣugbọn ọpá Aaroni gbe ọpá wọn mì. Aiya Farao si le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.

Eks 7:1-13 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, “Wò ó, mo ti sọ ọ́ di ọlọrun fún Farao, Aaroni, arakunrin rẹ ni yóo sì jẹ́ wolii rẹ. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ; Aaroni, arakunrin rẹ yóo sì sọ fún Farao pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn n óo mú kí ọkàn Farao le, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo fi jẹ́ pé, bí ó ti wù kí iṣẹ́ ìyanu tí n óo ṣe ní ilẹ̀ Ijipti pọ̀ tó, kò ní gbọ́ tìrẹ. Nígbà náà ni n óo nawọ́ ìyà sí Ijipti, n óo sì kó àwọn ọmọ Israẹli, ìjọ eniyan mi, jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti pẹlu iṣẹ́ ìyanu ati ìdájọ́ ńlá. Àwọn ará Ijipti yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá nawọ́ ìyà sí Ijipti tí mo sì kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò láàrin wọn.” Mose ati Aaroni bá ṣe bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn. Nígbà tí Mose ati Aaroni lọ bá Farao sọ̀rọ̀, Mose jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún; Aaroni sì jẹ́ ẹni ọdún mẹtalelọgọrin. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Bí Farao bá wí pé kí ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan fún òun kí òun lè mọ̀ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, kí ìwọ Mose sọ fún Aaroni pé kí ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Farao ọba, kí ọ̀pá náà lè di ejò.” Mose ati Aaroni bá lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn. Aaroni ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Farao ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ọ̀pá náà di ejò. Farao bá pe gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n, ati àwọn oṣó, ati àwọn pidánpidán tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Ijipti, àwọn náà pa idán, wọ́n ṣe bí Aaroni ti ṣe. Olukuluku wọn sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀pá wọn sì di ejò ṣugbọn ọ̀pá Aaroni gbé gbogbo ọ̀pá tiwọn mì. Sibẹsibẹ ọkàn Farao tún le, kò sì gbọ́ tiwọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀.

Eks 7:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Wò ó, Èmi ti ṣe ọ bí Ọlọ́run fún Farao, Aaroni arákùnrin rẹ ni yóò jẹ́ wòlíì (agbẹnusọ) rẹ. Ìwọ yóò sì sọ ohun gbogbo tí Èmi ti pàṣẹ fún ọ, Aaroni arákùnrin rẹ yóò sísọ fún Farao kí ó jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi yóò sé Farao lọ́kàn le. Bí Mo tilẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì àti ìyanu ni Ejibiti, síbẹ̀ òun kì yóò fi etí sí ọ. Nígbà náà ni Èmi yóò gbé ọwọ́ mi lé Ejibiti, pẹ̀lú agbára ìdájọ́ ńlá mi ni èmi yóò mú àwọn ènìyàn mi Israẹli jáde ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Àwọn ará Ejibiti yóò sì mọ̀ pé Èmi ni OLúWA ní ìgbà tí mo bá na ọwọ́ mi jáde lé Ejibiti, tí mo sì mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò níbẹ̀.” Mose àti Aaroni sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún wọn. Mose jẹ́ ọmọ ọgọ́rin ọdún (80) Aaroni sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83) ni ìgbà tí wọ́n bá Farao sọ̀rọ̀. OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni, “Ní ìgbà tí Farao bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan,’ sọ fún Aaroni ní ìgbà náà pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ níwájú Farao,’ yóò sì di ejò.” Nígbà náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, wọ́n sì ṣe bí OLúWA ti pàṣẹ fún wọn, Aaroni ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ ní iwájú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò. Farao sì pe àwọn amòye, àwọn oṣó àti àwọn onídán ilẹ̀ Ejibiti jọ, wọ́n sì fi idán wọn ṣe ohun tí Mose àti Aaroni ṣe. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò. Ṣùgbọ́n ọ̀pá Aaroni gbé ọ̀pá tiwọn mì. Síbẹ̀ ọkàn Farao sì yigbì, kò si fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti sọ.