Eksodu 7:1-13

Eksodu 7:1-13 YCB

Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Wò ó, Èmi ti ṣe ọ bí Ọlọ́run fún Farao, Aaroni arákùnrin rẹ ni yóò jẹ́ wòlíì (agbẹnusọ) rẹ. Ìwọ yóò sì sọ ohun gbogbo tí Èmi ti pàṣẹ fún ọ, Aaroni arákùnrin rẹ yóò sísọ fún Farao kí ó jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi yóò sé Farao lọ́kàn le. Bí Mo tilẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì àti ìyanu ni Ejibiti, síbẹ̀ òun kì yóò fi etí sí ọ. Nígbà náà ni Èmi yóò gbé ọwọ́ mi lé Ejibiti, pẹ̀lú agbára ìdájọ́ ńlá mi ni èmi yóò mú àwọn ènìyàn mi Israẹli jáde ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Àwọn ará Ejibiti yóò sì mọ̀ pé Èmi ni OLúWA ní ìgbà tí mo bá na ọwọ́ mi jáde lé Ejibiti, tí mo sì mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò níbẹ̀.” Mose àti Aaroni sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún wọn. Mose jẹ́ ọmọ ọgọ́rin ọdún (80) Aaroni sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83) ni ìgbà tí wọ́n bá Farao sọ̀rọ̀. OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni, “Ní ìgbà tí Farao bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan,’ sọ fún Aaroni ní ìgbà náà pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ níwájú Farao,’ yóò sì di ejò.” Nígbà náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, wọ́n sì ṣe bí OLúWA ti pàṣẹ fún wọn, Aaroni ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ ní iwájú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò. Farao sì pe àwọn amòye, àwọn oṣó àti àwọn onídán ilẹ̀ Ejibiti jọ, wọ́n sì fi idán wọn ṣe ohun tí Mose àti Aaroni ṣe. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò. Ṣùgbọ́n ọ̀pá Aaroni gbé ọ̀pá tiwọn mì. Síbẹ̀ ọkàn Farao sì yigbì, kò si fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti sọ.