ẸKISODU 7

7
1OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, “Wò ó, mo ti sọ ọ́ di ọlọrun fún Farao, Aaroni, arakunrin rẹ ni yóo sì jẹ́ wolii rẹ. 2Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ; Aaroni, arakunrin rẹ yóo sì sọ fún Farao pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀. 3Ṣugbọn n óo mú kí ọkàn Farao le, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo fi jẹ́ pé, bí ó ti wù kí iṣẹ́ ìyanu tí n óo ṣe ní ilẹ̀ Ijipti pọ̀ tó, kò ní gbọ́ tìrẹ.#A. Apo 7:36. 4Nígbà náà ni n óo nawọ́ ìyà sí Ijipti, n óo sì kó àwọn ọmọ Israẹli, ìjọ eniyan mi, jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti pẹlu iṣẹ́ ìyanu ati ìdájọ́ ńlá. 5Àwọn ará Ijipti yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá nawọ́ ìyà sí Ijipti tí mo sì kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò láàrin wọn.” 6Mose ati Aaroni bá ṣe bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn. 7Nígbà tí Mose ati Aaroni lọ bá Farao sọ̀rọ̀, Mose jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún; Aaroni sì jẹ́ ẹni ọdún mẹtalelọgọrin.
Ọ̀pá Aaroni
8OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, 9“Bí Farao bá wí pé kí ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan fún òun kí òun lè mọ̀ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, kí ìwọ Mose sọ fún Aaroni pé kí ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Farao ọba, kí ọ̀pá náà lè di ejò.” 10Mose ati Aaroni bá lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn. Aaroni ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Farao ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ọ̀pá náà di ejò. 11Farao bá pe gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n, ati àwọn oṣó, ati àwọn pidánpidán tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Ijipti, àwọn náà pa idán, wọ́n ṣe bí Aaroni ti ṣe. 12Olukuluku wọn sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀pá wọn sì di ejò ṣugbọn ọ̀pá Aaroni gbé gbogbo ọ̀pá tiwọn mì. 13Sibẹsibẹ ọkàn Farao tún le, kò sì gbọ́ tiwọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀.
Ìṣẹ̀lẹ̀ Burúkú ṣẹ̀ ní Ijipti
Omi Di Ẹ̀jẹ̀
14OLUWA wí fún Mose pé, “Ọkàn Farao ti le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan náà lọ. 15Tọ Farao lọ ní òwúrọ̀, bí ó bá ti ń jáde lọ sí etídò, kí o dúró dè é ní etí bèbè odò, kí o sì mú ọ̀pá tí ó di ejò lọ́wọ́. 16Sọ fún un pé, ‘OLUWA, Ọlọrun àwọn Heberu rán mi sí ọ, pé kí o jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ, kí wọ́n lè sin òun ní aṣálẹ̀, sibẹ o kò gbọ́. 17OLUWA wí pé ohun tí o óo fi mọ̀ pé òun ni OLUWA nìyí: n óo fi ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ mi yìí lu odò Naili, omi odò náà yóo sì di ẹ̀jẹ̀.#Ifi 16:4 18Gbogbo ẹja inú odò náà yóo kú, odò náà yóo sì máa rùn, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti kò ní lè mu omi inú rẹ̀ mọ́.’ ”
19OLUWA rán Mose pé, “Sọ fún Aaroni pé kí ó mú ọ̀pá rẹ̀, kí ó sì nà án sí orí gbogbo omi ilẹ̀ Ijipti, ati sórí odò wọn, ati sórí adágún tí wọ́n gbẹ́, ati gbogbo ibi tí omi dárogún sí, kí wọ́n lè di ẹ̀jẹ̀, ẹ̀jẹ̀ yóo sì wà níbi gbogbo jákèjádò ilẹ̀ Ijipti; ati omi tí ó wà ninu agbada tí wọ́n fi igi gbẹ́, ati tinú agbada tí wọ́n fi òkúta gbẹ́.”
20Mose ati Aaroni ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA lójú Farao ati lójú gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Aaroni gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ó sì fi lu omi tí ó wà ninu odò Naili, gbogbo omi tí ó wà ninu odò náà sì di ẹ̀jẹ̀. 21Gbogbo ẹja tí ó wà ninu odò náà kú, odò sì bẹ̀rẹ̀ sí rùn tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti kò fi lè mu omi rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ sì wà níbi gbogbo jákèjádò ilẹ̀ Ijipti. 22Ṣugbọn àwọn pidánpidán ilẹ̀ Ijipti lo ọgbọ́n idán wọn, àwọn náà ṣe bí Mose ati Aaroni ti ṣe, tí ó fi jẹ́ pé ọkàn Farao túbọ̀ yigbì sí i, kò sì gbọ́ ohun tí Mose ati Aaroni wí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀. 23Dípò bẹ́ẹ̀, Farao yipada, ó lọ sí ilé, kò ka ọ̀rọ̀ náà sí rara. 24Gbogbo àwọn ará Ijipti bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́lẹ̀ káàkiri yíká odò Naili, pé bóyá wọn á jẹ́ rí omi mímu nítorí pé wọn kò lè mu omi odò Naili mọ́.#Ọgb 11:6-8
25Ọjọ́ meje kọjá, lẹ́yìn tí OLUWA ti fi ọ̀pá lu odò Naili.
Ọ̀pọ̀lọ́ Bo Ilẹ̀

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ẸKISODU 7: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀