Deu 33:18-29

Deu 33:18-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ati niti Sebuluni o wipe, Sebuluni, ma yọ̀ ni ijade rẹ; ati Issakari, ninu agọ́ rẹ. Nwọn o pè awọn enia na sori òke; nibẹ̀ ni nwọn o ru ẹbọ ododo: nitoripe nwọn o ma mu ninu ọ̀pọlọpọ okun, ati ninu iṣura ti a pamọ́ ninu iyanrin. Ati niti Gadi o wipe, Ibukún ni fun ẹniti o mu Gadi gbilẹ: o ba bi abo-kiniun, o si fà apa ya, ani atari. O si yàn apá ikini fun ara rẹ̀, nitoripe nibẹ̀ li a fi ipín olofin pamọ́ si; o si wá pẹlu awọn olori enia na, o si mú ododo OLUWA ṣẹ, ati idajọ rẹ̀ pẹlu Israeli. Ati niti Dani o wipe, Ọmọ kiniun ni Dani: ti nfò lati Baṣani wá. Ati niti Naftali o wipe, Iwọ Naftali, ti ojurere tẹ́lọrùn, ti o si kún fun ibukún OLUWA: gbà ìha ìwọ-õrùn ati gusù. Ati niti Aṣeri o wipe, Ibukún ọmọ niti Aṣeri; ki on ki o si jẹ́ itẹwọgba fun awọn arakunrin rẹ̀, ki on ki o si ma rì ẹsẹ̀ rẹ̀ sinu oróro. Bàta rẹ yio jasi irin ati idẹ; ati bi ọjọ́ rẹ, bẹ̃li agbara rẹ yio ri. Kò sí ẹniti o dabi Ọlọrun, iwọ Jeṣuruni, ti ngùn ọrun fun iranlọwọ rẹ, ati ninu ọlanla rẹ̀ li oju-ọrun. Ọlọrun aiyeraiye ni ibugbé rẹ, ati nisalẹ li apa aiyeraiye wà: on si tì ọtá kuro niwaju rẹ, o si wipe, Ma parun. Israeli si joko li alafia, orisun Jakobu nikan, ni ilẹ ọkà ati ti ọti-waini; pẹlupẹlu ọrun rẹ̀ nsẹ̀ ìri silẹ. Alafia ni fun iwọ, Israeli: tali o dabi rẹ, iwọ enia ti a ti ọwọ́ OLUWA gbàla, asà iranlọwọ rẹ, ati ẹniti iṣe idà ọlanla rẹ! awọn ọtá rẹ yio si tẹriba fun ọ; iwọ o si ma tẹ̀ ibi giga wọn mọlẹ.

Deu 33:18-29 Yoruba Bible (YCE)

Ó súre fún Sebuluni ati fún Isakari, ó ní: “Máa yọ̀ bí o ti ń jáde lọ, ìwọ Sebuluni, sì máa yọ̀ ninu ilé rẹ, ìwọ Isakari. Wọn óo pe àwọn àlejò jọ sórí òkè, wọn óo sì máa rú ẹbọ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ níbẹ̀. Nítorí wọn óo máa kó ọrọ̀ jọ láti inú òkun, ati dúkìá tí ó farasin láti inú yanrìn etí òkun.” Ìre tí ó sú fún ẹ̀yà Gadi ni pé: “Ibukun ni fún ẹni tí ó bukun ilẹ̀ Gadi, Gadi dàbí kinniun tí ó ba láti fani lápá ya, ati láti géni lórí. Ibi tí ó dára jùlọ ninu ilẹ̀ náà ni wọ́n mú fún ara wọn, nítorí pé ibẹ̀ ni ìpín olórí ogun wà, ó wá sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn eniyan náà, àtòun, àtàwọn eniyan náà sì ń pa àṣẹ OLUWA mọ́, wọn sì ń ṣe ìdájọ́ òdodo.” Ó súre fun ẹ̀yà Dani pé: “Dani dàbí ẹgbọ̀rọ̀ kinniun, tí ó fò jáde láti Baṣani.” Ó súre fún ẹ̀yà Nafutali pé: “OLUWA ti ṣíjú rere wo Nafutali, ó sì ti bukun un lọpọlọpọ, ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti adágún Galili, títí lọ kan gúsù gbọ̀ngbọ̀n.” Ìre tí ó sú fún ẹ̀yà Aṣeri ni pé: “Ibukun ẹ̀yà Aṣeri ta gbogbo ibukun ẹ̀yà yòókù yọ, àyànfẹ́ ni yóo jẹ́ láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, ilẹ̀ rẹ̀ yóo sì kún fún òróró olifi. Ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn rẹ̀ yóo jẹ́ irin ati idẹ, bí iye ọjọ́ orí rẹ̀ bá ti tó, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóo pọ̀ tó.” Ẹ̀yin ará Jeṣuruni, kò sí ẹni tí ó dàbí Ọlọrun yín, tí ó gun awọsanma lẹ́ṣin ninu ọlá ńlá rẹ̀, láti wá ràn yín lọ́wọ́. Ọlọrun ayérayé ni ààbò yín, ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi ń gbé yín ró. Bí ẹ ti ń súnmọ́ wájú, bẹ́ẹ̀ ni ó ń lé àwọn ọ̀tá yín jáde, tí ó sì ní kí ẹ máa pa wọ́n run. Nítorí náà, Israẹli wà ní alaafia, àwọn ọmọ Jakọbu sì ń gbé láìléwu, ní ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati ọtí waini, tí ìrì sì ń sẹ̀ sórí rẹ̀ láti ọ̀run wá. Ẹ máa fò fún ayọ̀, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ta ló tún dàbí yín, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí OLUWA tìkalárarẹ̀ gbàlà? OLUWA tìkalárarẹ̀ ni ààbò yín, ati idà yín, òun ní ń dáàbò bò yín, tí ó sì ń fun yín ní ìṣẹ́gun. Àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa wá bẹ̀bẹ̀ fún àánú, ẹ óo sì máa tẹ àwọn pẹpẹ ìrúbọ wọn mọ́lẹ̀.

Deu 33:18-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ti Sebuluni ó wí pé: “Yọ̀ Sebuluni, ní ti ìjáde lọ rẹ, àti ìwọ Isakari, nínú àgọ́ rẹ. Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkè àti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo, wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òkun, nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.” Ní ti Gadi ó wí pé: “Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gadi gbilẹ̀! Gadi ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún, ó sì fa apá ya, àní àtàrí. Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀; ìpín olórí ni a sì fi fún un. Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ, ó mú òdodo OLúWA ṣẹ, àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli.” Ní ti Dani ó wí pé: “Ọmọ kìnnìún ni Dani, tí ń fò láti Baṣani wá.” Ní ti Naftali ó wí pé: “Ìwọ Naftali, kún fún ojúrere Ọlọ́run àti ìbùkún OLúWA; yóò jogún ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gúúsù.” Ní ti Aṣeri ó wí pé: “Ìbùkún ọmọ ni ti Aṣeri; jẹ́ kí ó rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kí ó sì ri ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú òróró. Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ, agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀. “Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jeṣuruni, ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ àti ní ojú ọ̀run nínú ọláńlá rẹ̀. Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ, àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà. Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ, ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’ Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà, orísun Jakọbu nìkan ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì, níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀. Ìbùkún ni fún ọ, Israẹli, ta ni ó dàbí rẹ, ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ OLúWA? Òun ni asà àti ìrànwọ́ rẹ̀ àti idà ọláńlá rẹ̀. Àwọn ọ̀tá rẹ yóò tẹríba fún ọ, ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”