Deu 33:18-29

Deu 33:18-29 YBCV

Ati niti Sebuluni o wipe, Sebuluni, ma yọ̀ ni ijade rẹ; ati Issakari, ninu agọ́ rẹ. Nwọn o pè awọn enia na sori òke; nibẹ̀ ni nwọn o ru ẹbọ ododo: nitoripe nwọn o ma mu ninu ọ̀pọlọpọ okun, ati ninu iṣura ti a pamọ́ ninu iyanrin. Ati niti Gadi o wipe, Ibukún ni fun ẹniti o mu Gadi gbilẹ: o ba bi abo-kiniun, o si fà apa ya, ani atari. O si yàn apá ikini fun ara rẹ̀, nitoripe nibẹ̀ li a fi ipín olofin pamọ́ si; o si wá pẹlu awọn olori enia na, o si mú ododo OLUWA ṣẹ, ati idajọ rẹ̀ pẹlu Israeli. Ati niti Dani o wipe, Ọmọ kiniun ni Dani: ti nfò lati Baṣani wá. Ati niti Naftali o wipe, Iwọ Naftali, ti ojurere tẹ́lọrùn, ti o si kún fun ibukún OLUWA: gbà ìha ìwọ-õrùn ati gusù. Ati niti Aṣeri o wipe, Ibukún ọmọ niti Aṣeri; ki on ki o si jẹ́ itẹwọgba fun awọn arakunrin rẹ̀, ki on ki o si ma rì ẹsẹ̀ rẹ̀ sinu oróro. Bàta rẹ yio jasi irin ati idẹ; ati bi ọjọ́ rẹ, bẹ̃li agbara rẹ yio ri. Kò sí ẹniti o dabi Ọlọrun, iwọ Jeṣuruni, ti ngùn ọrun fun iranlọwọ rẹ, ati ninu ọlanla rẹ̀ li oju-ọrun. Ọlọrun aiyeraiye ni ibugbé rẹ, ati nisalẹ li apa aiyeraiye wà: on si tì ọtá kuro niwaju rẹ, o si wipe, Ma parun. Israeli si joko li alafia, orisun Jakobu nikan, ni ilẹ ọkà ati ti ọti-waini; pẹlupẹlu ọrun rẹ̀ nsẹ̀ ìri silẹ. Alafia ni fun iwọ, Israeli: tali o dabi rẹ, iwọ enia ti a ti ọwọ́ OLUWA gbàla, asà iranlọwọ rẹ, ati ẹniti iṣe idà ọlanla rẹ! awọn ọtá rẹ yio si tẹriba fun ọ; iwọ o si ma tẹ̀ ibi giga wọn mọlẹ.