DIUTARONOMI 33:18-29

DIUTARONOMI 33:18-29 YCE

Ó súre fún Sebuluni ati fún Isakari, ó ní: “Máa yọ̀ bí o ti ń jáde lọ, ìwọ Sebuluni, sì máa yọ̀ ninu ilé rẹ, ìwọ Isakari. Wọn óo pe àwọn àlejò jọ sórí òkè, wọn óo sì máa rú ẹbọ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ níbẹ̀. Nítorí wọn óo máa kó ọrọ̀ jọ láti inú òkun, ati dúkìá tí ó farasin láti inú yanrìn etí òkun.” Ìre tí ó sú fún ẹ̀yà Gadi ni pé: “Ibukun ni fún ẹni tí ó bukun ilẹ̀ Gadi, Gadi dàbí kinniun tí ó ba láti fani lápá ya, ati láti géni lórí. Ibi tí ó dára jùlọ ninu ilẹ̀ náà ni wọ́n mú fún ara wọn, nítorí pé ibẹ̀ ni ìpín olórí ogun wà, ó wá sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn eniyan náà, àtòun, àtàwọn eniyan náà sì ń pa àṣẹ OLUWA mọ́, wọn sì ń ṣe ìdájọ́ òdodo.” Ó súre fun ẹ̀yà Dani pé: “Dani dàbí ẹgbọ̀rọ̀ kinniun, tí ó fò jáde láti Baṣani.” Ó súre fún ẹ̀yà Nafutali pé: “OLUWA ti ṣíjú rere wo Nafutali, ó sì ti bukun un lọpọlọpọ, ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti adágún Galili, títí lọ kan gúsù gbọ̀ngbọ̀n.” Ìre tí ó sú fún ẹ̀yà Aṣeri ni pé: “Ibukun ẹ̀yà Aṣeri ta gbogbo ibukun ẹ̀yà yòókù yọ, àyànfẹ́ ni yóo jẹ́ láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, ilẹ̀ rẹ̀ yóo sì kún fún òróró olifi. Ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn rẹ̀ yóo jẹ́ irin ati idẹ, bí iye ọjọ́ orí rẹ̀ bá ti tó, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóo pọ̀ tó.” Ẹ̀yin ará Jeṣuruni, kò sí ẹni tí ó dàbí Ọlọrun yín, tí ó gun awọsanma lẹ́ṣin ninu ọlá ńlá rẹ̀, láti wá ràn yín lọ́wọ́. Ọlọrun ayérayé ni ààbò yín, ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi ń gbé yín ró. Bí ẹ ti ń súnmọ́ wájú, bẹ́ẹ̀ ni ó ń lé àwọn ọ̀tá yín jáde, tí ó sì ní kí ẹ máa pa wọ́n run. Nítorí náà, Israẹli wà ní alaafia, àwọn ọmọ Jakọbu sì ń gbé láìléwu, ní ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati ọtí waini, tí ìrì sì ń sẹ̀ sórí rẹ̀ láti ọ̀run wá. Ẹ máa fò fún ayọ̀, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ta ló tún dàbí yín, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí OLUWA tìkalárarẹ̀ gbàlà? OLUWA tìkalárarẹ̀ ni ààbò yín, ati idà yín, òun ní ń dáàbò bò yín, tí ó sì ń fun yín ní ìṣẹ́gun. Àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa wá bẹ̀bẹ̀ fún àánú, ẹ óo sì máa tẹ àwọn pẹpẹ ìrúbọ wọn mọ́lẹ̀.