II. A. Ọba 17:6-7
II. A. Ọba 17:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Li ọdun kẹsan Hoṣea, ni ọba Assiria kó Samaria, o si kó Israeli lọ si Assiria, o si fi wọn si Hala ati si Habori, leti odò Gosani, ati si ilu awọn ara Media. O si ṣe, nitoriti awọn ọmọ Israeli dẹṣẹ si Oluwa Ọlọrun wọn, ti o ti mu wọn gòke lati ilẹ Egipti wá, kuro labẹ ọwọ Farao ọba Egipti, ti nwọn si mbẹ̀ru ọlọrun miran.
II. A. Ọba 17:6-7 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọdún kẹsan-an tí Hoṣea jọba, ọba Asiria ṣẹgun Samaria, ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbèkùn lọ sí Asiria. Ó kó wọn sí ìlú Hala ati sí etí odò Habori tí ó wà ní agbègbè Gosani, ati sí àwọn ìlú Media. Ogun kó Samaria nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun wọn ó gbà wọ́n lọ́wọ́ ọba Farao, tí ó sì kó wọn jáde kúrò ní Ijipti. Wọ́n ti bọ oriṣa
II. A. Ọba 17:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọdún kẹsànán ti Hosea, ọba Asiria mú Samaria ó sì kó Israẹli lọ sí Asiria. Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ní Hala, ní Gosani ní etí odò Habori àti ní ìlú àwọn ará Media. Gbogbo eléyìí ṣẹlẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli ti dẹ́ṣẹ̀ sí OLúWA Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde ní Ejibiti lábẹ́ agbára Farao ọba Ejibiti. Wọ́n sin ọlọ́run mìíràn