II. A. Ọba 17

17
Hoṣea Ọba Israẹli
1LI ọdun kejila Ahasi ọba Juda ni Hoṣea ọmọ Ela bẹ̀rẹ si ijọba ni Samaria, lori Israeli li ọdun mẹsan.
2O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, ṣugbọn kì iṣe bi awọn ọba Israeli ti o ti wà ṣãju rẹ̀.
3On ni Ṣalamaneseri ọba Assiria gòke tọ̀ wá; Hoṣea si di iranṣẹ rẹ̀, o si ta a li ọrẹ.
4Ọba Assiria si ri ọ̀tẹ ninu Hoṣea: nitoriti o ti rán onṣẹ sọdọ So ọba Egipti, kò si mu ọrẹ fun ọba Assiria wá bi iti mã iṣe li ọdọdun; nitorina ni ọba Assiria há a mọ, o si dè e ni ile tubu.
5Nigbana ni ọba Assiria gòke wá si gbogbo ilẹ na, o si gòke lọ si Samaria, o si dotì i li ọdun mẹta.
Ìṣubú Samaria
6Li ọdun kẹsan Hoṣea, ni ọba Assiria kó Samaria, o si kó Israeli lọ si Assiria, o si fi wọn si Hala ati si Habori, leti odò Gosani, ati si ilu awọn ara Media.
7O si ṣe, nitoriti awọn ọmọ Israeli dẹṣẹ si Oluwa Ọlọrun wọn, ti o ti mu wọn gòke lati ilẹ Egipti wá, kuro labẹ ọwọ Farao ọba Egipti, ti nwọn si mbẹ̀ru ọlọrun miran.
8Ti nwọn si nrìn ninu ilana awọn keferi, ti Oluwa ti le jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli, ati ti awọn ọba Israeli, ti nwọn ti ṣe.
9Awọn ọmọ Israeli si ṣe ohun ikọ̀kọ ti kò tọ́ si Oluwa Ọlọrun wọn, nwọn si kọ́ ibi giga fun ara wọn ni gbogbo ilu wọn, lati ile-iṣọ awọn olùṣọ titi de ilu olodi.
10Nwọn si gbé awọn ere kalẹ, nwọn si dá ere oriṣa si lori òke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo:
11Nibẹ ni nwọn si sun turari ni gbogbo ibi giga wọnni, bi awọn keferi ti Oluwa kó lọ niwaju wọn ti ṣe; nwọn si ṣe ohun buburu lati rú ibinu Oluwa soke.
12Nitoriti nwọn sìn oriṣa wọnni, eyiti Oluwa ti wi fun wọn pe, Ẹnyin kò gbọdọ ṣe nkan yi.
13Sibẹ Oluwa jẹri si Israeli, ati si Juda, nipa ọwọ gbogbo awọn woli, ati gbogbo awọn ariran, wipe, Ẹ yipada kuro ninu ọ̀na buburu nyin, ki ẹ si pa ofin mi ati ilana mi mọ́, gẹgẹ bi gbogbo ofin ti mo pa li aṣẹ fun awọn baba nyin, ti mo rán si nyin nipa ọwọ awọn woli iranṣẹ mi.
14Sibẹ nwọn kò fẹ igbọ́, ṣugbọn nwọn mu ọrùn wọn le, gẹgẹ bi ọrùn awọn baba wọn, ti kò gbà Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́.
15Nwọn si kọ̀ ilana rẹ̀, ati majẹmu rẹ̀ silẹ, ti o ba awọn baba wọn dá, ati ẹri rẹ̀ ti o jẹ si wọn: nwọn si ntọ̀ ohun asan lẹhin, nwọn si huwa asan, nwọn si ntọ̀ awọn keferi lẹhin ti o yi wọn ka, niti ẹniti Oluwa ti kilọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe ṣe bi awọn.
16Nwọn si kọ̀ gbogbo ofin Oluwa Ọlọrun wọn silẹ, nwọn si ṣe ere didà fun ara wọn, ani, ẹgbọ̀rọ malu meji, nwọn si ṣe ere oriṣa, nwọn si mbọ gbogbo ogun ọrun, nwọn si sìn Baali.
17Nwọn si mu ki awọn ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn ki o kọja lãrin iná, nwọn si nfọ̀ afọ̀ṣẹ, nwọn si nṣe alupayida, nwọn si tà ara wọn lati ṣe ibi niwaju Oluwa, lati mu u binu.
18Nitorina ni Oluwa ṣe binu si Israeli gidigidi, o si mu wọn kuro niwaju rẹ̀: ọkan kò kù bikòṣe ẹ̀ya Juda nikanṣoṣo.
19Juda pẹlu kò pa aṣẹ Oluwa Ọlọrun wọn mọ́, ṣugbọn nwọn rìn ninu ilana Israeli ti nwọn ṣe.
20Oluwa si kọ̀ gbogbo iru-ọmọ Israeli silẹ, o si wahala wọn, o si fi wọn le awọn akoni lọwọ, titi o si fi ta wọn nù kuro niwaju rẹ̀.
21Nitori ti o yà Israeli kuro ni idile Dafidi; nwọn si fi Jeroboamu ọmọ Nebati jọba: Jeroboamu si tì Israeli kuro lati má tọ̀ Oluwa lẹhin, o si mu wọn ṣẹ̀ ẹ̀ṣẹ nla.
22Nitoriti awọn ọmọ Israeli rìn ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ti o ṣẹ̀; nwọn kò lọ kuro ninu wọn;
23Titi Oluwa fi mu Israeli kuro niwaju rẹ̀, bi o ti sọ nipa gbogbo awọn woli iranṣẹ rẹ̀. Bẹ̃li a kó Israeli kuro ni ilẹ wọn lọ si Assiria, titi di oni yi.
Àwọn Ará Asiria Bẹ̀rẹ̀ sí Gbé Ilẹ̀ Israẹli
24Ọba Assiria si kó enia lati Babeli wá, ati lati Kuta, ati lati Afa, ati lati Hamati, ati lati Sefarfaimi, o si fi wọn sinu ilu Samaria wọnni, ni ipò awọn ọmọ Israeli; nwọn si ni Samaria, nwọn si ngbe inu rẹ̀ wọnni.
25O si ṣe li atètekọ-gbé ibẹ wọn, nwọn kò bẹ̀ru Oluwa: nitorina ni Oluwa ṣe rán awọn kiniun sãrin wọn, ti o pa ninu wọn.
26Nitorina ni nwọn ṣe sọ fun ọba Assiria wipe, Awọn orilẹ-ède ti iwọ ṣi kuro, ti o si fi sinu ilu Samaria wọnni, kò mọ̀ iṣe Ọ̀lọrun ilẹ na: nitorina li on ṣe rán awọn kiniun sãrin wọn, si kiyesi i, nwọn pa wọn, nitoriti nwọn kò mọ̀ iṣe Ọlọrun ilẹ na.
27Nigbana li ọba Assiria paṣẹ, wipe, Ẹ mu ọkan ninu awọn alufa ti ẹnyin ti kó ti ọhún wá lọ sibẹ; ẹ si jẹ ki wọn ki o lọ igbe ibẹ, ki ẹ si jẹ ki o ma kọ́ wọn ni iṣe Ọlọrun ilẹ na.
28Nigbana ni ọkan ninu awọn alufa ti nwọn ti kó ti Samaria lọ, wá, o si joko ni Beteli, o si kọ́ wọn bi nwọn o ti mã bẹ̀ru Oluwa.
29Ṣugbọn olukuluku orilẹ-ède ṣe oriṣa tirẹ̀, nwọn si fi wọn sinu ile ibi giga wọnni ti awọn ara Samaria ti ṣe, olukuluku orilẹ-ède ninu ilu ti nwọn ngbe.
30Awọn enia Babeli ṣe agọ awọn wundia, ati awọn enia Kuti ṣe oriṣa Nergali, ati awọn enia Hamati ṣe ti Aṣima,
31Ati awọn ara Afa ṣe ti Nibhasi ati ti Tartaki, ati awọn ara Sefarfaimu sun awọn ọmọ wọn ninu iná fun Adrammeleki ati Anammeleki awọn òriṣa Sefarfaimu.
32Nwọn bẹ̀ru Oluwa pẹlu, nwọn si ṣe alufa ibi giga wọnni fun ara wọn, ninu awọn enia lasan, ti nrubọ fun wọn ni ile ibi giga wọnni.
33Nwọn bẹ̀ru Oluwa, nwọn si nsìn oriṣa wọn gẹgẹ bi iṣe awọn orilẹ-ède, ti nwọn kó lati ibẹ lọ.
34Titi di oni yi nwọn nṣe bi iṣe wọn atijọ: nwọn kò bẹ̀ru Oluwa, bẹ̃ni nwọn kò ṣe bi idasilẹ wọn, tabi ilàna wọn, tabi ofin ati aṣẹ ti Oluwa pa fun awọn ọmọ Jakobu, ti o sọ ni Israeli;
35Awọn ẹniti Oluwa ti ba dá majẹmu, ti o si ti kilọ fun wọn, wipe, Ẹnyin kò gbọdọ bẹ̀ru awọn ọlọrun miran, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ tẹ̀ ara nyin ba fun wọn, tabi ki ẹ sìn wọn, tabi ki ẹ rubọ si wọn:
36Ṣugbọn Oluwa ti o mu nyin gòke ti ilẹ Egipti wá, pẹlu agbara nla ati ninà apá, on ni ki ẹ mã bẹ̀ru, on ni ki ẹ si mã tẹriba fun, on ni ki ẹ sì mã rubọ si.
37Ati idasilẹ wọnni, ati ilàna wọnni, ati ofin ati aṣẹ ti o ti kọ fun nyin, li ẹnyin o mã kiyesi lati mã ṣe li ọjọ gbogbo; ẹnyin kò si gbọdọ bẹ̀ru awọn ọlọrun miràn.
38Ati majẹmu ti mo ti ba nyin dá ni ẹnyin kò gbọdọ gbàgbe; bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ bẹ̀ru awọn ọlọrun miran.
39Ṣugbọn Oluwa Ọlọrun nyin ni ẹnyin o mã bẹ̀ru; on ni yio si gbà nyin lọwọ awọn ọta nyin gbogbo.
40Nwọn kò si gbọ́, ṣugbọn nwọn ṣe bi iṣe wọn atijọ.
41Bẹ̃li awọn orilẹ-ède wọnyi bẹ̀ru Oluwa, ṣugbọn nwọn tun sin awọn ere fifin wọn pẹlu; awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ-ọmọ wọn, bi awọn baba wọn ti ṣe, bẹ̃li awọn na nṣe titi fi di oni yi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. A. Ọba 17: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀