II. A. Ọba 13:20-21
II. A. Ọba 13:20-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Eliṣa si kú, nwọn si sìn i. Ẹgbẹ́ awọn ara Moabu si gbé ogun wá ilẹ na li amọdun. O si ṣe, bi nwọn ti nsinkú ọkunrin kan, si kiye si i, nwọn ri ẹgbẹ́ kan; nwọn si jù ọkunrin na sinu isà-okú Eliṣa; nigbati a si sọ ọ silẹ, ti ọkunrin na fi ara kàn egungun Eliṣa, o si sọji, o si dide duro li ẹsẹ̀ rẹ̀.
II. A. Ọba 13:20-21 Yoruba Bible (YCE)
Eliṣa kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀. Ní ọdọọdún ni àwọn ọmọ ogun Moabu máa ń gbógun ti ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Ní ìgbà kan, bí wọ́n ti fẹ́ máa sìnkú ọkunrin kan, wọ́n rí i tí àwọn ọmọ ogun Moabu ń bọ̀, wọ́n bá ju òkú náà sinu ibojì Eliṣa. Bí ọkunrin náà ti fi ara kan egungun Eliṣa, ó sọjí, ó sì dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.
II. A. Ọba 13:20-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Eliṣa kú a sì sin ín. Ẹgbẹ́ Àwọn ará Moabu máa ń wọ orílẹ̀-èdè ní gbogbo àmọ́dún. Bí àwọn ọmọ Israẹli kan ti ń sin òkú ọkùnrin kan, lójijì wọ́n rí ẹgbẹ́ àwọn oníjadì: Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Eliṣa. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan egungun Eliṣa, ó padà wá sí ayé, ó sì dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀.