ÀWỌN ỌBA KEJI 13:20-21

ÀWỌN ỌBA KEJI 13:20-21 YCE

Eliṣa kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀. Ní ọdọọdún ni àwọn ọmọ ogun Moabu máa ń gbógun ti ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Ní ìgbà kan, bí wọ́n ti fẹ́ máa sìnkú ọkunrin kan, wọ́n rí i tí àwọn ọmọ ogun Moabu ń bọ̀, wọ́n bá ju òkú náà sinu ibojì Eliṣa. Bí ọkunrin náà ti fi ara kan egungun Eliṣa, ó sọjí, ó sì dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.