II. Kro 1:6-12
II. Kro 1:6-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Solomoni si lọ si ibi pẹpẹ idẹ niwaju Oluwa, ti o ti wà nibi agọ ajọ, o si rú ẹgbẹrun ẹbọ-sisun lori rẹ̀. Li oru na li Oluwa fi ara hàn Solomoni, o si wi fun u pe, Bère ohun ti emi o fi fun ọ. Solomoni si wi fun Ọlọrun pe, Iwọ ti fi ãnu nla hàn baba mi, o si ti mu mi jọba ni ipò rẹ̀. Nisisiyi Oluwa Ọlọrun, jẹ ki a mu ọ̀rọ rẹ fun Dafidi baba mi ṣẹ: nitoriti iwọ ti fi mi jọba lori awọn enia ti o pọ̀ bi erupẹ ilẹ. Fun mi li ọgbọ́n ati ìmọ nisisiyi, ki emi le ma wọ ile, ki nsi ma jade niwaju enia yi: nitoripe, tani le ṣe idajọ enia rẹ yi ti o pọ̀ to yi. Ọlọrun si wi fun Solomoni pe, Nitoriti eyi wà li aiya rẹ, ti iwọ kò si bère ọrọ̀, ọlà, tabi ọlá, tabi ẹmi awọn ọta rẹ, bẹ̃ni o kò tilẹ bère ẹmi gigun, ṣugbọn o bère ọgbọ́n fun ara rẹ, ki o le ma ṣe idajọ enia mi, lori ẹniti mo fi ọ jọba: Nitorina a fi ọgbọ́n on ìmọ fun ọ, Emi o si fun ọ ni ọrọ̀, ọlá, tabi ọlà, iru eyiti ọba kan ninu awọn ti nwọn wà ṣaju rẹ kò ni ri, bẹ̃ni lẹhin rẹ kì yio si ẹniti yio ni iru rẹ̀.
II. Kro 1:6-12 Yoruba Bible (YCE)
Ó lọ sí ìdí pẹpẹ bàbà tí ó wà níwájú OLUWA ninu àgọ́ àjọ, ó sì fi ẹgbẹrun (1,000) ẹran rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀. Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọrun fara han Solomoni, ó wí fún un pé “Bèèrè ohun tí o bá fẹ́ kí n fún ọ.” Solomoni dá Ọlọrun lóhùn, ó ní “O ti fi ìfẹ́ ńlá tí kìí yẹ̀ han Dafidi, baba mi, o sì ti fi mí jọba nípò rẹ̀. OLUWA, Ọlọrun, mú ìlérí tí o ṣe fún Dafidi, baba mi, ṣẹ nisinsinyii, nítorí pé o ti fi mí jọba lórí àwọn eniyan tí wọ́n pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀. Fún mi ní ọgbọ́n ati ìmọ̀ tí n óo fi máa ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi, nítorí pé ó ṣòro fún ẹnikẹ́ni láti ṣe àkóso àwọn eniyan rẹ tí wọ́n pọ̀ tó báyìí.” Ọlọrun dá Solomoni lóhùn pé, “Nítorí pé irú èrò yìí ló wà lọ́kàn rẹ, ati pé o kò sì tọrọ nǹkan ìní, tabi ọrọ̀, ọlá, tabi ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ, o kò tilẹ̀ tọrọ ẹ̀mí gígùn, ṣugbọn ọgbọ́n ati ìmọ̀ ni o tọrọ, láti máa ṣe àkóso àwọn eniyan mi tí mo fi ọ́ jọba lé lórí, n óo fún ọ ní ọgbọ́n ati ìmọ̀; n óo sì fún ọ ní ọrọ̀, nǹkan ìní, ati ọlá, irú èyí tí ọba kankan ninu àwọn tí wọ́n ti jẹ ṣiwaju rẹ kò tíì ní rí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní sí èyí tí yóo jẹ lẹ́yìn rẹ tí yóo ní irú rẹ̀.”
II. Kro 1:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Solomoni gòkè lọ sí ibi pẹpẹ idẹ níwájú OLúWA ní ibi àgọ́ ìpàdé, ó sì rú ẹgbẹ̀rún ẹbọ sísun lórí rẹ̀. Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọ́run farahàn Solomoni, ó sì wí fún un pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ kí n fún ọ.” Solomoni dá Ọlọ́run lóhùn pé, “Ìwọ ti fi àánú ńlá han Dafidi baba mi, ìwọ sì ti fi mí jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Nísinsin yìí OLúWA Ọlọ́run, jẹ́ kí ìlérí rẹ sí baba à mi Dafidi wá sí ìmúṣẹ, nítorí ìwọ ti fi mí jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀. Fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀, kí èmi kí ó lè máa wọ ilé kí ń sì máa jáde níwájú ènìyàn wọ̀nyí, nítorí ta ni ó le è ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ tí ó pọ̀ yanturu wọ̀nyí?” Ọlọ́run wí fún Solomoni pé, “Níwọ́n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìfẹ́ ọkàn rẹ nìyí, tí ìwọ kò sì béèrè, fún ọrọ̀, ọlá tàbí ọ̀wọ̀, tàbí fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, àti nígbà tí ìwọ kò ti béèrè fún ẹ̀mí gígùn, ṣùgbọ́n tí ìwọ béèrè fún ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti ṣàkóso àwọn ènìyàn mi tí èmi fi ọ́ jẹ ọba lé lórí, Nítorí náà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni a ó fi fún ọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ọrọ̀, ọlá àti ọ̀wọ̀, irú èyí tí ọba ti ó wà ṣáájú rẹ kò ní, tí àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ kò sì ní ní irú rẹ̀.”