II. Kro 1

1
Solomoni Ọba Gbadura fún Ọgbọ́n
(I. A. Ọba 3:1-15)
1A si mu Solomoni, ọmọ Dafidi, lagbara lori ijọba rẹ̀, Oluwa Ọlọrun rẹ̀ si wà pẹlu rẹ̀, o si gbé e ga gidigidi.
2Solomoni si sọ fun gbogbo Israeli, fun awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati fun awọn onidajọ, ati fun gbogbo awọn bãlẹ ni gbogbo Israeli, awọn olori awọn baba.
3Solomoni ati gbogbo awọn ijọ enia pẹlu rẹ̀, lọ si ibi giga ti o wà ni Gibeoni; nitori nibẹ ni agọ ajọ enia Ọlọrun gbe wà, ti Mose, iranṣẹ Oluwa ti pa ni aginju.
4Apoti-ẹri Ọlọrun ni Dafidi ti gbé lati Kirjat-jearimu wá si ibi ti Dafidi ti pese silẹ fun u, nitoriti o ti pa agọ kan silẹ fun u ni Jerusalemu.
5Ṣugbọn pẹpẹ idẹ ti Besaleeli, ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ṣe, wà nibẹ niwaju agọ Oluwa: Solomoni ati ijọ enia si wá a ri.
6Solomoni si lọ si ibi pẹpẹ idẹ niwaju Oluwa, ti o ti wà nibi agọ ajọ, o si rú ẹgbẹrun ẹbọ-sisun lori rẹ̀.
7Li oru na li Oluwa fi ara hàn Solomoni, o si wi fun u pe, Bère ohun ti emi o fi fun ọ.
8Solomoni si wi fun Ọlọrun pe, Iwọ ti fi ãnu nla hàn baba mi, o si ti mu mi jọba ni ipò rẹ̀.
9Nisisiyi Oluwa Ọlọrun, jẹ ki a mu ọ̀rọ rẹ fun Dafidi baba mi ṣẹ: nitoriti iwọ ti fi mi jọba lori awọn enia ti o pọ̀ bi erupẹ ilẹ.
10Fun mi li ọgbọ́n ati ìmọ nisisiyi, ki emi le ma wọ ile, ki nsi ma jade niwaju enia yi: nitoripe, tani le ṣe idajọ enia rẹ yi ti o pọ̀ to yi.
11Ọlọrun si wi fun Solomoni pe, Nitoriti eyi wà li aiya rẹ, ti iwọ kò si bère ọrọ̀, ọlà, tabi ọlá, tabi ẹmi awọn ọta rẹ, bẹ̃ni o kò tilẹ bère ẹmi gigun, ṣugbọn o bère ọgbọ́n fun ara rẹ, ki o le ma ṣe idajọ enia mi, lori ẹniti mo fi ọ jọba:
12Nitorina a fi ọgbọ́n on ìmọ fun ọ, Emi o si fun ọ ni ọrọ̀, ọlá, tabi ọlà, iru eyiti ọba kan ninu awọn ti nwọn wà ṣaju rẹ kò ni ri, bẹ̃ni lẹhin rẹ kì yio si ẹniti yio ni iru rẹ̀.
Agbára Solomoni ati Ọrọ̀ Rẹ̀
(I. A. Ọba 10:26-29)
13Solomoni si pada lati ibi giga ti o wà ni Gibeoni wá si Jerusalemu, lati iwaju agọ ajọ awọn enia, o si jọba lori Israeli.
14Solomoni ko kẹkẹ́ ati awọn ẹlẹṣin jọ: o si ni ẹgbãje kẹkẹ́ ati ẹgbãfa ẹlẹṣin, ti o fi sinu ilu kẹkẹ́ ati pẹlu ọba ni Jerusalemu.
15Ọba si ṣe ki fadakà ati wura ki o wà ni Jerusalemu bi okuta, ati igi kedari li o ṣe ki o dabi igi sikamore ti o wà ni afonifoji fun ọ̀pọlọpọ.
16A si mu ẹṣin wá fun Solomoni lati Egipti, ati okùn-ọ̀gbọ: awọn oniṣowo ọba ngbà okùn-ọ̀gbọ na ni iye kan.
17Nwọn si gòke, nwọn si mu kẹkẹ́ kan lati Egipti wá fun ẹgbẹta ṣekeli fadakà, ati ẹṣin kan fun ãdọjọ: bẹ̃ni nwọn si nmu ẹṣin jade fun gbogbo awọn ọba ara Hitti, ati fun awọn ọba Siria nipa wọn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Kro 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀