II. Kro Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Kronika Keji bẹ̀rẹ̀ ìtàn rẹ̀ níbi tí Kronika Kinni parí tirẹ̀ sí. Ó sọ àwọn ohun tí Ọba Solomoni ṣe lórí oyè títí tí ó fi kú. Ninu ìwé yìí, a ní àkọsílẹ̀ bí Jeroboamu ṣe darí àwọn ẹ̀yà àríwá Israẹli, tí wọ́n ya kúrò lábẹ́ Rehoboamu, tí ó jọba lẹ́yìn Solomoni, baba rẹ̀; lẹ́yìn náà a tún ní àkọsílẹ̀ ìtàn ìjọba ìpínlẹ̀ gúsù Juda, títí di ìgbà tí wọ́n kó Jerusalẹmu nígbèkùn ní ẹgbẹta ọdún ó dín mẹrinla, kí á tó bí OLUWA wa (586 B.C.)
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Àkókò ìjọba Solomoni 1:1—9:31
a. Àwọn ọdún tí Solomoni kọ́kọ́ lò lórí oyè 1:1-17
b. Bí wọ́n ṣe kọ́ Tẹmpili parí 2:1—7:10
d. Àwọn ọdún tí Solomoni lò kẹ́yìn lórí oyè 7:11—9:31
Bí àwọn ẹ̀yà ìhà àríwá ṣe ya lọ 10:1-19
Àwọn Ọba Juda 11:1—36:12
Ìṣubú Jerusalẹmu 36:13-23

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Kro Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀