II. Kro 1:6-12

II. Kro 1:6-12 YBCV

Solomoni si lọ si ibi pẹpẹ idẹ niwaju Oluwa, ti o ti wà nibi agọ ajọ, o si rú ẹgbẹrun ẹbọ-sisun lori rẹ̀. Li oru na li Oluwa fi ara hàn Solomoni, o si wi fun u pe, Bère ohun ti emi o fi fun ọ. Solomoni si wi fun Ọlọrun pe, Iwọ ti fi ãnu nla hàn baba mi, o si ti mu mi jọba ni ipò rẹ̀. Nisisiyi Oluwa Ọlọrun, jẹ ki a mu ọ̀rọ rẹ fun Dafidi baba mi ṣẹ: nitoriti iwọ ti fi mi jọba lori awọn enia ti o pọ̀ bi erupẹ ilẹ. Fun mi li ọgbọ́n ati ìmọ nisisiyi, ki emi le ma wọ ile, ki nsi ma jade niwaju enia yi: nitoripe, tani le ṣe idajọ enia rẹ yi ti o pọ̀ to yi. Ọlọrun si wi fun Solomoni pe, Nitoriti eyi wà li aiya rẹ, ti iwọ kò si bère ọrọ̀, ọlà, tabi ọlá, tabi ẹmi awọn ọta rẹ, bẹ̃ni o kò tilẹ bère ẹmi gigun, ṣugbọn o bère ọgbọ́n fun ara rẹ, ki o le ma ṣe idajọ enia mi, lori ẹniti mo fi ọ jọba: Nitorina a fi ọgbọ́n on ìmọ fun ọ, Emi o si fun ọ ni ọrọ̀, ọlá, tabi ọlà, iru eyiti ọba kan ninu awọn ti nwọn wà ṣaju rẹ kò ni ri, bẹ̃ni lẹhin rẹ kì yio si ẹniti yio ni iru rẹ̀.