I. Sam 14:47-52
I. Sam 14:47-52 Bibeli Mimọ (YBCV)
Saulu si jọba lori Israeli; o si bá gbogbo awọn ọta rẹ̀ jà yika, eyini ni Moabu ati awọn ọmọ Ammoni, ati Edomu, ati awọn ọba Soba ati awọn Filistini: ati ibikibi ti o yi si, a bà wọn ninu jẹ. O si ko ogun jọ, o si kọlu awọn Amaleki, o si gbà Israeli silẹ lọwọ awọn ti o nkó wọn. Awọn ọmọ Saulu si ni Jonatani, ati Iṣui, ati Malkiṣua; ati orukọ ọmọbinrin rẹ̀ mejeji si ni wọnyi; orukọ akọbi ni Merabu, ati orukọ aburo ni Mikali: Ati orukọ aya Saulu ni Ahinoamu, ọmọbinrin Ahimaasi, ati orukọ olori ogun rẹ̀ ni Abneri ọmọ Neri arakunrin baba Saulu. Kiṣi si ni baba Saulu; ati Neri ni baba Abneri ọmọ Abieli. Ogun na si le si awọn Filistini ni gbogbo ọjọ Saulu: bi Saulu ba ri ẹnikan ti o li agbara, tabi akikanju ọkunrin, a mu u sọdọ rẹ̀.
I. Sam 14:47-52 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn tí Saulu ti di ọba Israẹli tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọ̀tá tí wọ́n yí i ká jagun; àwọn bíi: Moabu, Amoni, ati Edomu, ọba ilẹ̀ Soba, ati ti ilẹ̀ Filistini. Ní gbogbo ibi tí ó ti jagun ni ó ti pa wọ́n ní ìpakúpa. Ó jagun gẹ́gẹ́ bí akikanju, ó ṣẹgun àwọn ará Amaleki. Ó sì gba Israẹli kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fi ogun kó wọn. Àwọn ọmọ Saulu lọkunrin ni Jonatani, Iṣifi, ati Malikiṣua. Orúkọ ọmọbinrin rẹ̀ àgbà ni Merabu, ti èyí àbúrò ni Mikali. Ahinoamu ọmọ Ahimaasi ni aya Saulu. Abineri ọmọ Neri, arakunrin baba Saulu, sì ni balogun rẹ̀. Kiṣi ni baba Saulu. Neri, baba Abineri jẹ́ ọmọ Abieli. Gbogbo ọjọ́ ayé Saulu ni ó fi bá àwọn ará Filistia jagun kíkankíkan. Nígbà gbogbo tí Saulu bá sì ti rí ọkunrin tí ó jẹ́ alágbára tabi akikanju, a máa fi kún àwọn ọmọ ogun rẹ̀.
I. Sam 14:47-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ìgbà tí Saulu ti jẹ ọba lórí Israẹli, ó sì bá gbogbo ọ̀tá wọn jà yíká: Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni; Edomu, àti àwọn ọba Ṣoba, àti àwọn Filistini. Ibikíbi tí ó bá kọjú sí, ó máa ń fi ìyà jẹ wọ́n. Ó sì jà tagbára tagbára, ó ṣẹ́gun àwọn Amaleki, ó sì ń gba Israẹli sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ń kọlù wọ́n. Àwọn ọmọ Saulu sì ni Jonatani, Iṣifi àti Malikiṣua. Orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà sì ni Merabu àti orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ni Mikali. Orúkọ ìyàwó rẹ̀ ní Ahinoamu ọmọbìnrin Ahimasi. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Abneri ọmọ Neri arákùnrin baba Saulu. Kiṣi baba Saulu àti Neri baba Abneri wọ́n sì jẹ́ ọmọ Abieli. Ní gbogbo ọjọ́ Saulu, ogun náà sì gbóná sí àwọn Filistini, níbikíbi tí Saulu bá sì ti rí alágbára tàbí akíkanjú ọkùnrin, a sì mú u láti máa bá a ṣiṣẹ́.