SAMUẸLI KINNI 14

14
Jonatani Hùwà Akikanju
1Ní ọjọ́ kan, Jonatani, ọmọ Saulu, wí fún ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí á lọ sí òdìkejì ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini.” Ṣugbọn Jonatani kò sọ fún Saulu, baba rẹ̀. 2Ní àkókò yìí, baba rẹ̀ pàgọ́ ogun rẹ̀ sí abẹ́ igi pomegiranate kan ní Migironi, nítòsí Gibea. Àwọn ọmọ ogun bíi ẹgbẹta (600) wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. 3Ẹni tí ó jẹ́ alufaa tí ó ń wọ ẹ̀wù efodu nígbà náà ni Ahija, ọmọ Ahitubu, arakunrin Ikabodu, ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, tíí ṣe alufaa OLUWA ní Ṣilo. Àwọn ọmọ ogun kò mọ̀ pé Jonatani ti kúrò lọ́dọ̀ àwọn.
4Àwọn òkúta ńláńlá meji kan wà ní ọ̀nà kan, tí ó wà ní àfonífojì Mikimaṣi. Pàlàpálá òkúta wọnyi ni Jonatani gbà lọ sí ibùdó ogun àwọn Filistini. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn òkúta náà wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ọ̀nà náà. Orúkọ ekinni ń jẹ́ Bosesi, ekeji sì ń jẹ́ Sene. 5Èyí ekinni wà ní apá àríwá ọ̀nà náà, ó dojú kọ Mikimaṣi. Ekeji sì wà ní apá gúsù, ó dojú kọ Geba.
6Jonatani bá pe ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó ní, “Jẹ́ kí á rékọjá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Filistia, àwọn aláìkọlà wọnyi, bóyá OLUWA a jẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Bí OLUWA bá fẹ́ ran eniyan lọ́wọ́, kò sí ohun tí ó lè dí i lọ́wọ́, kì báà jẹ́ pé eniyan pọ̀ ni, tabi wọn kò pọ̀.”
7Ọdọmọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Ohunkohun tí ọkàn rẹ bá fẹ́ ni kí o ṣe. Mo wà lẹ́yìn rẹ, bí ọkàn rẹ ti rí ni tèmi náà rí.”
8Jonatani bá dáhùn pé, “Ó dára, a óo rékọjá sọ́hùn-ún, a óo sì fi ara wa han àwọn ará Filistia. 9Bí wọ́n bá ní kí á dúró kí àwọn tọ̀ wá wá, a óo dúró níbi tí a bá wà, a kò ní lọ sọ́dọ̀ wọn. 10Ṣugbọn bí wọ́n bá ní kí á máa bọ̀ lọ́dọ̀ àwọn, a óo tọ̀ wọ́n lọ. Èyí ni yóo jẹ́ àmì fún wa, pé OLUWA ti fún wa ní ìṣẹ́gun lórí wọn.”
11Nítorí náà, wọ́n fi ara wọn han àwọn ará Filistia. Bí àwọn ara Filistia ti rí wọn, wọ́n ní, “Ẹ wò ó! Àwọn Heberu ń jáde bọ̀ wá láti inú ihò òkúta tí wọ́n farapamọ́ sí.” 12Wọ́n bá nahùn pe Jonatani ati ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀; wọ́n ní, “Ẹ máa gòkè tọ̀ wá bọ̀ níhìn-ín, a óo fi nǹkankan hàn yín.”
Jonatani bá wí fún ọdọmọkunrin náà pé, “Tẹ̀lé mi, OLUWA ti fún Israẹli ní ìṣẹ́gun lórí wọn.” 13Jonatani bá rápálá gun òkè náà, ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Jonatani bá bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ará Filistia jà, wọ́n sì ń ṣubú níwájú rẹ̀, bí wọ́n ti ń ṣubú ni ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ ń pa wọ́n. 14Ní àkókò tí wọ́n kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n, Jonatani ati ọdọmọkunrin yìí pa nǹkan bí ogún eniyan. Ààrin ibi tí wọ́n ti ja ìjà yìí kò ju nǹkan bí ìdajì sarè oko kan lọ. 15Ẹ̀rù ba gbogbo àwọn ará Filistia tí wọ́n wà ní ibùdó, ati àwọn tí wọ́n wà ninu pápá, ati gbogbo eniyan. Àwọn ọmọ ogun Filistini ati àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n ń digun-jalè wárìrì, ilẹ̀ mì tìtì, jìnnìjìnnì sì dà bo gbogbo wọn.
Àwọn Ọmọ Ogun Israẹli Ṣẹgun Àwọn ti Filistini
16Àwọn ọmọ ogun Saulu tí wọn ń ṣọ́nà ní Gibea, ní agbègbè Bẹnjamini, rí i tí àwọn ọmọ ogun Filistini ń sá káàkiri. 17Saulu bá pàṣẹ fún àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n ka gbogbo àwọn ọmọ ogun, láti mọ àwọn tí wọ́n jáde kúrò láàrin wọn. Wọ́n bá ka àwọn ọmọ ogun, wọ́n sì rí i pé Jonatani ati ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ kò sí láàrin wọn. 18Saulu wí fún Ahija, alufaa pé, “Gbé àpótí Ọlọrun wá níhìn-ín.” Nítorí àpótí Ọlọrun ń bá àwọn ọmọ ogun Israẹli lọ ní àkókò náà. 19Bí Saulu ti ń bá alufaa náà sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìdàrúdàpọ̀ tí ó wà ninu àgọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini ń pọ̀ sí i. Nítorí náà, Saulu wí fún un pé kí ó dáwọ́ dúró. 20Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó ara wọn jọ, wọ́n lọ sójú ogun náà. Wọ́n bá àwọn ọmọ ogun ninu ìdàrúdàpọ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ara wọn. 21Àwọn Heberu tí wọ́n ti wà lẹ́yìn àwọn ará Filistia tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì bá wọn lọ sí ibùdó ogun wọn, yipada kúrò lẹ́yìn wọn, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun Israẹli tí wọ́n wà pẹlu Saulu ati Jonatani. 22Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti farapamọ́ káàkiri agbègbè olókè Efuraimu gbọ́ pé àwọn ará Filistia ti bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ; wọ́n yára dara pọ̀ mọ́ Saulu, wọ́n dojú ìjà kọ àwọn ọmọ ogun Filistini. 23Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe ṣẹgun fún àwọn ọmọ Israẹli ní ọjọ́ náà, wọ́n sì ja ogun náà kọjá Betafeni.
Àwọn Ohun tí Ó Ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn Ogun
24Ara àwọn ọmọ ogun Israẹli ti hù ní ọjọ́ náà, àárẹ̀ sì mú wọn, nítorí pé Saulu ti fi ìbúra pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ẹnu kan nǹkankan títí di àṣáálẹ́ ọjọ́ náà, títí tí òun yóo fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá òun, olúwarẹ̀ gbé! Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni ninu wọn tí ó fi ẹnu kan nǹkankan. 25Gbogbo wọn dé inú igbó, wọ́n rí oyin nílẹ̀. 26Nígbà tí wọ́n wọ inú igbó náà, wọ́n rí i tí oyin ń kán sílẹ̀, ṣugbọn kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè fi ọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìbúra Saulu. 27Ṣugbọn Jonatani kò gbọ́ nígbà tí baba rẹ̀ ń fi ìbúra pàṣẹ fún àwọn eniyan náà. Nítorí náà, ó na ọ̀pá tí ó mú lọ́wọ́, ó tì í bọ inú afárá oyin kan, ó sì lá a. Lẹsẹkẹsẹ ojú rẹ̀ wálẹ̀. 28Ọ̀kan ninu àwọn eniyan náà wí fún un pé, “Ebi ń pa gbogbo wa kú lọ, ṣugbọn baba rẹ ti búra pé, ‘Ègbé ni fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ẹnu kan nǹkankan lónìí.’ ”
29Jonatani dáhùn pé, “Ohun tí baba mi ṣe sí àwọn eniyan wọnyi kò dára, wò ó bí ojú mi ti wálẹ̀ nígbà tí mo lá oyin díẹ̀. 30Báwo ni ìbá ti dára tó lónìí, bí ó bá jẹ́ pé àwọn eniyan jẹ lára ìkógun àwọn ọ̀tá wọn tí wọ́n rí. Àwọn ará Filistia tí wọn ìbá pa ìbá ti pọ̀ ju èyí lọ.”
31Wọ́n pa àwọn ọmọ ogun Filistini ní ọjọ́ náà, láti Mikimaṣi títí dé Aijaloni; ó sì rẹ àwọn eniyan náà gidigidi. 32Nítorí náà, wọ́n sáré sí ìkógun, wọ́n pa àwọn aguntan ati mààlúù ati ọmọ mààlúù, wọ́n sì ń jẹ wọ́n tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀. 33Wọ́n bá lọ sọ fún Saulu pé, “Àwọn eniyan ń dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nítorí wọ́n ń jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.”#Jẹn 9:4; Lef 7:26-27; 17:10-14; 19:26; Diut 12:16,23;15:23.
Saulu bá wí pé, “Ìwà ọ̀dàlẹ̀ ni ẹ hù yìí. Ẹ yí òkúta ńlá kan wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín.” 34Ó tún pàṣẹ pé, “Ẹ lọ sí ààrin àwọn eniyan, kí ẹ sì wí fún wọn pé, kí wọ́n kó mààlúù wọn ati aguntan wọn wá síhìn-ín. Níhìn-ín ni kí wọ́n ti pa wọ́n, kí wọ́n sì jẹ wọ́n. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀, kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA.” Nítorí náà, gbogbo wọn kó mààlúù wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Saulu ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀. 35Saulu bá tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA. Pẹpẹ yìí ni pẹpẹ kinni tí Saulu tẹ́ fún OLUWA.
36Saulu wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ kọlu àwọn ará Filistia ní òru kí á kó ẹrù wọn, kí á sì pa gbogbo wọn títí ilẹ̀ yóo fi mọ́ láì dá ẹnikẹ́ni sí.”
Àwọn eniyan náà dá a lóhùn pé, “Ṣe èyí tí ó bá dára lójú rẹ.”
Ṣugbọn alufaa wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọ́kọ́ bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun ná.”
37Saulu bá bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun pé, “Ṣé kí n lọ kọlu àwọn ará Filistia? Ṣé o óo fún Israẹli ní ìṣẹ́gun?” Ṣugbọn Ọlọrun kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà. 38Saulu bá pe gbogbo olórí àwọn eniyan náà jọ, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí á wádìí ohun tí ó fa ẹ̀ṣẹ̀ òní. 39Mo fi OLUWA alààyè tí ó fún Israẹli ní ìṣẹ́gun búra pé, pípa ni a óo pa ẹni tí ó bá jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí, kì báà jẹ́ Jonatani ọmọ mi.” Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò dá a lóhùn ninu wọn. 40Saulu bá wí fún gbogbo Israẹli pé, “Gbogbo yín, ẹ dúró ní apá kan, èmi ati Jonatani, ọmọ mi, yóo dúró ní apá keji.”
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ.”
41Saulu bá ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí ló dé tí o kò fi dá iranṣẹ rẹ lóhùn lónìí? OLUWA Ọlọrun Israẹli, bí ó bá jẹ́ pé èmi tabi Jonatani ni a jẹ̀bi, fi Urimu dáhùn. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé àwọn eniyan rẹ ni wọ́n ṣẹ̀, fi Tumimu dáhùn.” Urimu bá mú Jonatani ati Saulu, 42Saulu ní, “Ẹ ṣẹ́ gègé láàrin èmi ati Jonatani, ọmọ mi.” Gègé bá mú Jonatani. 43Saulu bèèrè lọ́wọ́ Jonatani pé kí ó sọ ohun tí ó ṣe fún òun.#Nọm 27:21; 1 Sam 28:6.
Jonatani dá a lóhùn pé, “Mo ti ọ̀pá tí mo mú lọ́wọ́ bọ inú oyin, mo sì lá a. Èmi nìyí, mo ṣetán láti kú.”
44Saulu dá a lóhùn pé, “Láì sí àní àní, pípa ni wọn yóo pa ọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí Ọlọrun lù mí pa.”
45Nígbà náà ni àwọn eniyan wí fún Saulu pé, “Ṣé a óo pa Jonatani ni, ẹni tí ó ti ṣẹ́ ogun ńlá fún Israẹli? Kí á má rí i. Bí OLUWA tí ń bẹ láàyè, ẹyọ irun orí rẹ̀ kan kò ní bọ́ sílẹ̀. Agbára Ọlọrun ni ó fi ṣe ohun tí ó ṣe lónìí.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan náà ṣe gba Jonatani kalẹ̀, tí wọn kò sì jẹ́ kí wọ́n pa á.
46Lẹ́yìn èyí, Saulu kò lépa àwọn ará Filistia mọ́. Àwọn Filistini sì pada lọ sí agbègbè wọn.
Ìjọba ati Ìdílé Saulu
47Lẹ́yìn tí Saulu ti di ọba Israẹli tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọ̀tá tí wọ́n yí i ká jagun; àwọn bíi: Moabu, Amoni, ati Edomu, ọba ilẹ̀ Soba, ati ti ilẹ̀ Filistini. Ní gbogbo ibi tí ó ti jagun ni ó ti pa wọ́n ní ìpakúpa. 48Ó jagun gẹ́gẹ́ bí akikanju, ó ṣẹgun àwọn ará Amaleki. Ó sì gba Israẹli kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fi ogun kó wọn.
49Àwọn ọmọ Saulu lọkunrin ni Jonatani, Iṣifi, ati Malikiṣua. Orúkọ ọmọbinrin rẹ̀ àgbà ni Merabu, ti èyí àbúrò ni Mikali. 50Ahinoamu ọmọ Ahimaasi ni aya Saulu. Abineri ọmọ Neri, arakunrin baba Saulu, sì ni balogun rẹ̀. 51Kiṣi ni baba Saulu. Neri, baba Abineri jẹ́ ọmọ Abieli.
52Gbogbo ọjọ́ ayé Saulu ni ó fi bá àwọn ará Filistia jagun kíkankíkan. Nígbà gbogbo tí Saulu bá sì ti rí ọkunrin tí ó jẹ́ alágbára tabi akikanju, a máa fi kún àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SAMUẸLI KINNI 14: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀