I. Kro 23:30-31
I. Kro 23:30-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati lati duro li orowurọ lati dupẹ ati lati yin Oluwa, ati bẹ̃ gẹgẹ li aṣalẹ; Ati lati ru gbogbo ẹbọ ọrẹ sisun fun Oluwa li ọjọjọ isimi, ati li oṣù titun ati li ọjọ wọnni ti a pa li aṣẹ, ni iye, li ẹsẹsẹ gẹgẹ bi aṣẹ ti a pa fun wọn nigbagbogbo niwaju Oluwa
I. Kro 23:30-31 Yoruba Bible (YCE)
Wọn yóo máa kọrin ìyìn sí OLUWA ní àràárọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ní ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́, ati nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ń rúbọ sí OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ oṣù titun, tabi ọjọ́ àjọ̀dún, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn tí a yàn láti máa kọrin níwájú OLUWA nígbà gbogbo.
I. Kro 23:30-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin OLúWA. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àṣálẹ́. Àti láti rú ẹbọ sísun fún OLúWA ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú OLúWA lójoojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti pàṣẹ fún wọn.