I. Kro 23

23
Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi
1NIGBATI Dafidi gbó, ti o si kún fun ọjọ, o fi Solomoni ọmọ rẹ̀ jẹ ọba lori Israeli.
2O si kó gbogbo awọn ijoye Israeli jọ, ati awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi.
3A si ka awọn ọmọ Lefi lati ẹni ọgbọ̀n ọdun ati jù bẹ̃ lọ: iye wọn nipa ori wọn, ọkunrin kọkan sí jẹ ẹgbã mọkandilogun.
4Ninu wọnyi, ẹgbã mejila ni lati ma bojuto iṣẹ ile Oluwa; ẹgbãta si nṣe olori ati onidajọ:
5Ẹgbaji si jẹ adena: ẹgbaji si fi ohun-elo ti mo ṣe lati buyìn, yìn Oluwa.
6Dafidi si pín wọn ni ẹgbẹgbẹ lãrin awọn ọmọ Lefi, eyini ni Gerṣoni, Kohati, ati Merari.
7Ninu awọn ọmọ Gerṣoni ni Laadani, ati Ṣimei.
8Awọn ọmọ Laadani: Jehieli ni olori, ati Setamu, ati Joeli, mẹta.
9Awọn ọmọ Ṣimei; Ṣelomiti, ati Hasieli, ati Harani, mẹta. Awọn wọnyi li olori awọn baba Laadani.
10Awọn ọmọ Ṣimei ni Jahati, Sina, ati Jeuṣi, ati Beriah. Awọn mẹrin wọnyi li ọmọ Ṣimei.
11Jahati si li olori, ati Sisa ibikeji: ṣugbọn Jeuṣi ati Beriah kò li ọmọ pipọ; nitorina ni nwọn ṣe wà ni iṣiro kan, gẹgẹ bi ile baba wọn.
12Awọn ọmọ Kohati; Amramu, Ishari, Hebroni ati Ussieli, mẹrin.
13Awọn ọmọ Amramu; Aaroni ati Mose: a si ya Aaroni si ọ̀tọ, ki o le ma sọ awọn ohun mimọ́ jùlọ di mimọ́, on ati awọn ọmọ rẹ̀ lailai, lati ma jo turari niwaju Oluwa, lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀ lailai.
14Ṣugbọn niti Mose enia Ọlọrun, a kà awọn ọmọ rẹ̀ pọ̀ mọ ẹ̀ya Lefi.
15Awọn ọmọ Mose ni, Gerṣomu ati Elieseri.
16Ninu awọn ọmọ Gerṣomu, Sebueli li olori.
17Awọn ọmọ Elieseri ni Rehabiah olori. Elieseri kò si li ọmọ miran; ṣugbọn awọn ọmọ Rehabiah pọ̀ gidigidi.
18Ninu awọn ọmọ Ishari; Ṣelomiti li olori.
19Ninu awọn ọmọ Hebroni: Jeriah ekini, Amariah ekeji, Jahasieli ẹkẹta, ati Jekamami ẹkẹrin.
20Ninu awọn ọmọ Ussieli: Mika ekini, ati Jesiah ekeji.
21Awọn ọmọ Merari; Mali ati Muṣi. Awọn ọmọ Mali; Eleasari ati Kiṣi.
22Eleasari kú, kò si li ọmọkunrin bikòṣe ọmọbinrin: awọn arakunrin wọn awọn ọmọ Kiṣi si fẹ wọn li aiya.
23Awọn ọmọ Muṣi; Mali, ati Ederi, ati Jeremoti, mẹta.
24Wọnyi ni awọn ọmọ Lefi, bi ile baba wọn; ani olori awọn baba, bi a ti ka wọn ni iye orukọ, nipa ori wọn, awọn ti o ṣiṣẹ ìsin ile Oluwa, lati iwọn ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ.
25Nitori Dafidi wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli ti fi isimi fun awọn enia rẹ̀, on si ngbé Jerusalemu lailai:
26Ati pẹlu awọn ọmọ Lefi: nwọn kì yio si tun rù ibugbe na mọ, ati gbogbo ohun elo rẹ̀ fun ìsin rẹ̀.
27Nitori nipa ọ̀rọ ikẹhin Dafidi, ni kika iye awọn ọmọ Lefi lati ìwọn ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ:
28Nitori iṣẹ wọn ni lati duro tì awọn ọmọ Aaroni, fun ìsin ile Oluwa, niti àgbala, ati niti iyẹwu, ati niti ṣiṣe ohun èlo wọnni ni mimọ́, ati iṣẹ ìsin ile Ọlọrun;
29Ati fun àkara ifihàn, ati fun iyẹfun kikuna fun ẹbọ ọrẹ, ati fun àkara alaiwu, ati fun eyi ti a yan ninu awo pẹtẹ, ati fun eyi ti a dín, ati fun gbogbo oniruru òṣuwọn ati ìwọn;
30Ati lati duro li orowurọ lati dupẹ ati lati yin Oluwa, ati bẹ̃ gẹgẹ li aṣalẹ;
31Ati lati ru gbogbo ẹbọ ọrẹ sisun fun Oluwa li ọjọjọ isimi, ati li oṣù titun ati li ọjọ wọnni ti a pa li aṣẹ, ni iye, li ẹsẹsẹ gẹgẹ bi aṣẹ ti a pa fun wọn nigbagbogbo niwaju Oluwa:
32Ati ki nwọn ki o ma tọju ẹṣọ agọ ajọ enia, ati ẹṣọ ibi mimọ́, ati ẹṣọ awọn ọmọ Aaroni arakunrin wọn, ni ìsin ile Oluwa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 23: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀