I. Kro 22

22
1NIGBANA ni Dafidi wipe, Eyi ni ile Oluwa Ọlọrun, eyi si ni pẹpẹ ọrẹ-sisun fun Israeli.
Ìpalẹ̀mọ́ fún Kíkọ́ Tẹmpili
2Dafidi si paṣẹ lati ko awọn alejo ti mbẹ ni ilẹ Israeli jọ; o si yan awọn agbẹkuta lati gbẹ okuta lati fi kọ́le Ọlọrun.
3Dafidi si pese irin li ọ̀pọlọpọ fun iṣo fun ilẹkun ẹnu-ọ̀na, ati fun ìde; ati idẹ li ọ̀pọlọpọ li aini iwọn;
4Igi kedari pẹlu li ainiye: nitori awọn ara Sidoni, ati awọn ti Tire mu ọ̀pọlọpọ igi kedari wá fun Dafidi.
5Dafidi si wipe, Solomoni ọmọ mi, ọdọmọde ni, o si rọ̀, ile ti a o si kọ́ fun Oluwa, a o si ṣe e tobi jọjọ, fun okiki ati ogo ka gbogbo ilẹ: nitorina emi o pese silẹ fun u. Bẹ̃ni Dafidi si pese silẹ lọ̀pọlọpọ, ki o to kú.
6Nigbana li o pe Solomoni ọmọ rẹ̀, o si fi aṣẹ fun u lati kọ́le kan fun Oluwa Ọlọrun Israeli.
7Dafidi si wi fun Solomoni pe, Ọmọ mi, bi o ṣe ti emi ni, o ti wà li ọkàn mi lati kọ́le kan fun orukọ Oluwa Ọlọrun mi:
8Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, Iwọ ti ta ẹ̀jẹ silẹ li ọ̀pọlọpọ, iwọ si ti ja ogun nlanla: iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun orukọ mi, nitoriti iwọ ta ẹ̀jẹ pipọ̀ silẹ niwaju mi.
9Kiyesi i, a o bi ọmọ kan fun ọ, ẹniti yio ṣe enia isimi; emi o si fun u ni isimi lọdọ gbogbo awọn ọta rẹ̀ yika kiri: nitori orukọ rẹ̀ yio ma jẹ Solomoni, emi o si fi alafia ati idakẹjẹ fun Israeli li ọjọ aiye rẹ̀.
10On o kọ ile kan fun orukọ mi; on o si jẹ ọmọ mi; emi o si jẹ baba fun u; emi o si fi idi itẹ ijọba rẹ̀ mulẹ lori Israeli lailai.
11Njẹ ọmọ mi, ki Oluwa ki o pẹlu rẹ; iwọ si ma pọ̀ si i, ki o si kọ́ ile Oluwa Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ nipa tirẹ.
12Kiki ki Oluwa ki o fun ọ li ọgbọ́n ati oye, ki o si fun ọ li aṣẹ niti Israeli, ki iwọ ki o le pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ́.
13Nigbana ni iwọ o ma pọ̀ si i, bi iwọ ba ṣe akiyesi lati mu aṣẹ ati idajọ ti Oluwa pa fun Mose ṣẹ niti Israeli: mura giri ki o si ṣe onigboya, má bẹ̀ru bẹ̃ni ki aiya ki o máṣe fò ọ.
14Si kiyesi i, ninu ipọnju mi, emi ti pèse fun ile Oluwa na, ọkẹ marun talenti wura, ati ẹgbẹrun ẹgbẹrun talenti fadakà; ati ti idẹ, ati ti irin, laini ìwọn; nitori ọ̀pọlọpọ ni: ati ìti-igi ati okuta ni mo ti pèse; iwọ si le wá kún u.
15Pẹlupẹlu awọn oniṣẹ mbẹ fun ọ lọpọlọpọ, awọn gbẹnagbẹna ati awọn oniṣọna okuta ati igi ati onirũru ọlọgbọ́n enia fun onirũru iṣẹ.
16Niti wura, fadakà ati idẹ, ati irin, kò ni ìwọn. Nitorina dide ki o si ma ṣiṣẹ, ki Oluwa ki o si pẹlu rẹ.
17Dafidi paṣẹ pẹlu fun gbogbo awọn ijoye Israeli lati ran Solomoni ọmọ rẹ̀ lọwọ pe:
18Oluwa Ọlọrun nyin kò ha wà pẹlu nyin? on kò ha ti fi isimi fun nyin niha gbogbo? on sa ti fi awọn ti ngbe ilẹ na le mi li ọwọ; a si ṣẹgun ilẹ na niwaju Oluwa ati niwaju enia rẹ̀.
19Njẹ nisisiyi ẹ fi aiya nyin ati ọkàn nyin si atiwá Oluwa Ọlọrun nyin; nitorina dide ki ẹ si kọ́ ibi mimọ́ Oluwa Ọlọrun, lati mu apoti ẹri ti majẹmu Oluwa wọ̀ inu rẹ̀, ati ohun èlo mimọ́ Ọlọrun, sinu ile na ti a o kọ́ fun orukọ Oluwa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 22: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀