KRONIKA KINNI 23
23
1Nígbà tí Dafidi dàgbà, tí ó di arúgbó, ó fi Solomoni, ọmọ rẹ̀ jọba lórí Israẹli.
Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi
2Dafidi pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli, àwọn alufaa ati àwọn Lefi jọ. 3Ó ka gbogbo àwọn Lefi tí wọ́n jẹ́ ọkunrin tí wọ́n dàgbà tó ọmọ ọgbọ̀n ọdún sókè, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaa mọkandinlogun (38,000). 4Dafidi fún ẹgbaa mejila (24,000) ninu wọn ní iṣẹ́ ninu tẹmpili; ó ní kí ẹgbaata (6,000) máa ṣe àkọsílẹ̀ ati ìdájọ́ àwọn eniyan, 5kí ẹgbaaji (4,000) máa ṣọ́nà, kí ẹgbaaji (4,000) sì máa yin OLUWA pẹlu oríṣìíríṣìí ohun èlò orin tí ọba pèsè.
6Dafidi pín àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé ìdílé: ti Geriṣomu, ti Kohati, ati ti Merari.
7Àwọn ọmọ Geriṣomu jẹ́ meji: Ladani ati Ṣimei; 8Àwọn ọmọ Ladani jẹ́ mẹta: Jeieli tí ó jẹ́ olórí, Setamu ati Joẹli. 9Àwọn ọmọ Ṣimei ni Ṣelomoti, Hasieli, ati Harani; àwọn ni wọ́n jẹ́ olórí ìdílé Ladani. 10Àwọn ọmọ Ṣimei jẹ́ mẹrin: Jahati, Sina, Jeuṣi, ati Beraya. 11Jahati ni ó jẹ́ olórí, Sisa ni igbákejì rẹ̀, ṣugbọn Jeuṣi ati Beraya kò bí ọmọ pupọ, nítorí náà ni wọ́n fi kà wọ́n sí ìdílé kan ninu ọ̀kan ninu àwọn àkọsílẹ̀.#1A. Ọba 1:1-40
12Àwọn ọmọ Kohati jẹ́ mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni, ati Usieli, 13Àwọn ọmọ Amramu ni Aaroni ati Mose. Aaroni ni a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́, pé kí òun ati àwọn ìran rẹ̀ títí lae máa sun turari níwájú OLUWA, kí wọ́n máa darí ìsìn OLUWA, kí wọ́n sì máa súre fún àwọn eniyan ní orúkọ rẹ̀ títí lae. 14A ka àwọn ọmọ Mose, iranṣẹ Ọlọrun, pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀yà Lefi. 15Mose bí ọmọkunrin meji: Geriṣomu ati Elieseri. 16Àwọn ọmọ Geriṣomu ni: Ṣebueli, olórí ìdílé Geriṣomu. 17Elieseri bí ọmọkunrin kan tí ń jẹ́ Rehabaya, olórí ìdílé rẹ̀, kò sì bí ọmọ mìíràn mọ́, ṣugbọn àwọn ọmọ Rehabaya pọ̀.#Eks 28:1
18Iṣari bí ọmọkunrin kan, Ṣelomiti, tí ó jẹ́ olórí ìdílé rẹ̀. 19Heburoni bí ọmọ mẹrin: Jeraya, tí ó jẹ́ olórí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Amaraya, Jahasieli, Jekameamu. 20Usieli bí ọmọ meji: Mika, tí ó jẹ́ olórí, ati Iṣaya.
21Merari bí ọmọkunrin meji: Mahili ati Muṣi. Mahili bí ọmọkunrin meji: Eleasari ati Kiṣi, 22Ṣugbọn Eleasari kú láì ní ọmọkunrin kankan; kìkì ọmọbinrin ni ó bí. Àwọn ọmọbinrin rẹ̀ bá fẹ́ àwọn ọmọ Kiṣi, àbúrò baba wọn. 23Àwọn ọmọ Muṣi jẹ́ mẹta: Mahili, Ederi ati Jeremotu.
24Àwọn ni baálé baálé ninu ìran Lefi, ní ìdílé ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n tó ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n dàgbà tó láti ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA.
25Dafidi ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi, yóo sì máa gbé Jerusalẹmu títí lae. 26Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní máa ru Àgọ́ Àjọ ati àwọn ohun èlò tí wọn ń lò ninu rẹ̀ káàkiri mọ́.”#Diut 10:8
27Gẹ́gẹ́ bí ètò tí Dafidi ti ṣe, iye àwọn ọmọ Lefi láti ogún ọdún sókè nìyí: 28Ṣugbọn iṣẹ́ wọn ni láti máa ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ ninu iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA, láti máa ṣe ìtọ́jú àgbàlá ati àwọn yàrá ibẹ̀, láti rí i pé àwọn ohun èlò ilé OLUWA wà ní mímọ́, ati láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó yẹ ninu ilé OLUWA. 29Àwọn ni wọ́n tún ń ṣe ètò ṣíṣe burẹdi ìfihàn, ìyẹ̀fun fún ẹbọ ohun jíjẹ, àkàrà tí kò ní ìwúkàrà ninu, àkàrà díndín fún ẹbọ, ẹbọ tí a po òróró mọ́, ati pípèsè àwọn oríṣìíríṣìí ìwọ̀n. 30Wọn yóo máa kọrin ìyìn sí OLUWA ní àràárọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ní ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́, 31ati nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ń rúbọ sí OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ oṣù titun, tabi ọjọ́ àjọ̀dún, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn tí a yàn láti máa kọrin níwájú OLUWA nígbà gbogbo. 32Bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa bojútó Àgọ́ Àjọ ati ibi mímọ́, tí wọn yóo sì máa ran àwọn ọmọ Aaroni, àwọn arakunrin wọn lọ́wọ́, níbi iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA.#Nọm 3:5-9
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KRONIKA KINNI 23: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010