Orin Solomoni 4:9-10
Orin Solomoni 4:9-10 BMYO
Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; ìwọ ti gba ọkàn mi pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ, pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ. Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi! Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ, òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ!

