Romu 16:10-27

Romu 16:10-27 YCB

Ẹ kí Apelle, ẹni tí a mọ̀ dájú nínú Kristi. Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Aristobulu. Ẹ kí Herodioni, ìbátan mi. Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Narkissu tí wọ́n wá nínú Olúwa. Ẹ kí Trifena àti Trifosa, àwọn obìnrin tí wọ́n ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa. Ẹ kí Persi ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, obìnrin mìíràn tí ó ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa. Ẹ kí Rufusi, ẹni tí a yàn nínú Olúwa, àti ìyá rẹ̀ àti ẹni tí ó ti jẹ́ ìyá fún èmi náà pẹ̀lú. Ẹ kí Asinkritu, Flegoni, Herma, Patroba, Hermesi àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ó wà pẹ̀lú wọn. Ẹ kí Filologu, àti Julia, Nereu, àti arábìnrin rẹ̀, àti Olimpa, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà pẹ̀lú wọn. Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín. Gbogbo ìjọ Kristi kí yín. Èmí rọ̀ yín, ara, kí ẹ máa sọ àwọn tí ń fa ìyapa, àti àwọn tí ń mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá sí ọ̀nà yín, èyí tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ̀yin kọ́. Ẹ yà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. Nítorí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sin Kristi Olúwa wa, bí kò ṣe ikùn ara wọn. Nípa ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ dídùndídùn ni wọ́n fi ń yí àwọn aláìmọ̀kan ní ọkàn padà. Nítorí ìgbọ́ràn yín tànkálẹ̀ dé ibi gbogbo, nítorí náà mo ní ayọ̀ lórí yín; ṣùgbọ́n èmi fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n sí ohun tí ó ṣe rere, kí ẹ sì ṣe òpè sí ohun tí í ṣe búburú. Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Satani mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín. Timotiu alábáṣiṣẹ́ mi, àti Lukiu, àti Jasoni, àti Sosipateru, àwọn ìbátan mi, kí yín. Èmi Tertiu tí ń kọ lẹ́tà yìí, kí yín nínú Olúwa. Gaiu, ẹni tí èmi àti gbogbo ìjọ gbádùn ìtọ́jú wa tí ó ṣe náà fi ìkíni ránṣẹ́. Erastu, ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ìṣúra ìlú, àti arákùnrin wa Kuartu fi ìkíni wọn ránṣẹ́. Ǹjẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín. Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìhìnrere mi àti ìpolongo Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìṣípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé, ṣùgbọ́n, nísinsin yìí, a ti fihàn nípa ìwé mímọ́ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbọ́ràn tí ó wá láti inú ìgbàgbọ́; kí ògo wà fún Ọlọ́run, Ẹnìkan ṣoṣo tí ọgbọ́n í ṣe tirẹ̀ nípa Jesu Kristi títí láé! Àmín.