Rom 16:10-27

Rom 16:10-27 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ ki Apelle ẹniti a mọ̀ daju ninu Kristi. Ẹ kí awọn arãle Aristobulu. Ẹ kí Herodioni, ibatan mi. Ẹ kí awọn arãle Narkissu, ti o wà ninu Oluwa. Ẹ kí Trifena ati Trifosa, awọn ẹniti nṣe lãlã ninu Oluwa. Ẹ kí Persi olufẹ, ti o nṣe lãlã pipọ ninu Oluwa. Ẹ kí Rufu ti a yàn ninu Oluwa, ati iya rẹ̀ ati ti emi. Ẹ kí Asinkritu, Flegoni, Herma, Patroba, Herme, ati awọn arakunrin ti o wà pẹlu wọn. Ẹ kí Filologu, ati Julia, Nereu, ati arabinrin rẹ̀, ati Olimpa, ati gbogbo awọn enia mimọ́ ti o wà pẹlu wọn. Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ ki ara nyin. Gbogbo ijọ Kristi kí nyin. Ará, emi si bẹ̀ nyin, ẹ mã ṣọ awọn ti nṣe ìyapa, ati awọn ti nmu ohun ikọsẹ̀ wá lodi si ẹkọ́ ti ẹnyin kọ́; ẹ si kuro ni isọ wọn. Nitori awọn ti o ri bẹ̃ kò sìn Jesu Kristi Oluwa wa, bikoṣe ikùn ara wọn; ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ didùndidùn ni nwọn fi npa awọn ti kò mọ̀ meji li ọkàn dà. Nitori igbagbọ́ nyin tàn kalẹ de ìbi gbogbo. Nitorina mo ni ayọ̀ lori nyin: ṣugbọn emi fẹ ki ẹ jẹ ọlọgbọn si ohun ti o ṣe rere, ki ẹ si ṣe òpe si ohun ti iṣe buburu. Ọlọrun alafia yio si tẹ̀ Satani mọlẹ li atẹlẹsẹ nyin ni lọ̃lọ. Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa ki o wà pẹlu nyin. Amin. Timotiu, alabaṣiṣẹ mi, ati Lukiu, ati Jasoni, ati Sosipateru, awọn ibatan mi, ki nyin. Emi Tertiu ti nkọ Episteli yi, kí nyin ninu Oluwa. Gaiu, bãle mi, ati ti gbogbo ijọ, ki nyin. Erastu, olutọju iṣura ilu, kí nyin, ati Kuartu arakunrin. Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa, ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin. Njẹ fun ẹniti o li agbara lati fi ẹsẹ nyin mulẹ gẹgẹ bi ihinrere mi ati iwasu Jesu Kristi, gẹgẹ bi iṣipaya ohun ijinlẹ, ti a ti pamọ́ lati igba aiyeraiye, Ti a si nfihàn nisisiyi, ati nipa iwe-mimọ́ awọn woli, gẹgẹ bi ofin Ọlọrun aiyeraiye, ti a nfihàn fun gbogbo orilẹ-ède si igbọràn igbagbọ́: Ọlọrun ọlọ́gbọn nikanṣoṣo nipasẹ Jesu Kristi li ogo wà fun lailai. Amin.

Rom 16:10-27 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ kí Apele, akikanju onigbagbọ. Ẹ kí àwọn ará ilé Arisitobulu. Ẹ kí Hẹrodioni ìbátan mi. Ẹ kí àwọn ará ilé Nakisu tí wọ́n jẹ́ onigbagbọ. Ẹ kí Tirufina ati Tirufosa, àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ Oluwa. Ẹ kí Pasisi, arabinrin àyànfẹ́ tí ó ti ṣiṣẹ́ pupọ ninu Oluwa. Ẹ kí Rufọsi, àṣàyàn onigbagbọ ati ìyá rẹ̀ tí ó tún jẹ́ ìyá tèmi náà. Ẹ kí Asinkiritu, Filegọnta, Herime, Patiroba, Herima ati àwọn arakunrin tí ó wá pẹlu wọn. Ẹ kí Filologu ati Julia, Nerea ati arabinrin rẹ̀, ati Olimpa ati gbogbo àwọn onigbagbọ tí ó wà lọ́dọ̀ wọn. Ẹ rọ̀ mọ́ ara yín, kí ẹ sì kí ara yín pẹlu alaafia. Gbogbo ìjọ Kristi kí yín. Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín pé kí ẹ máa fura sí àwọn tí ó ń dá ìyapa sílẹ̀ ati àwọn tí ń múni ṣìnà, tí wọn ń ṣe àwọn nǹkan tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́, ẹ yẹra fún irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀. Nítorí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ kì í ṣe iranṣẹ Oluwa wa Kristi, ikùn ara wọn ni wọ́n ń bọ. Wọn a máa fi ọ̀rọ̀ dídùn ati kí á máa pọ́n eniyan tan àwọn tí kò bá fura jẹ. Ìròyìn ti tàn ká ibi gbogbo pé ẹ dúró ṣinṣin ninu igbagbọ. Èyí mú inú mi dùn nítorí yín. Mo fẹ́ kí ẹ jẹ́ amòye ninu nǹkan rere, ṣugbọn kí ẹ jẹ́ òpè ní ti àwọn nǹkan burúkú. Kí Ọlọrun orísun alaafia mu yín ṣẹgun Satani ní kíákíá. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu yín. Timoti alábàáṣiṣẹ́ mi ki yín. Bẹ́ẹ̀ náà ni Lukiusi ati Jasoni ati Sosipata, àwọn ìbátan wa. Èmi Tatiu tí mò ń bá Paulu kọ ìwé yìí ki yín: Ẹ kú iṣẹ́ Oluwa. Gaiyu náà ki yín. Òun ni ó gbà mí lálejò bí ó ti gba gbogbo ìjọ lálejò. Erastu, akápò ìlú, ki yín. Kuatu arakunrin wa náà ki yín. [ Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu gbogbo yín. Amin.] Ògo ni fún ẹni tí ó lágbára láti mu yín dúró gbọningbọnin, gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere ati iwaasu nípa Jesu Kristi ti wí ati gẹ́gẹ́ bí àdììtú tí Ọlọrun dì láti ayérayé, ṣugbọn tí ó wá tú ní àkókò yìí. Ìwé àwọn wolii ni ó ṣe ìṣípayá ohun tí ó fara pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọrun ayérayé, pé kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́, kí wọ́n mọ̀, kí wọ́n sì gbà. Ògo ni fún Ọlọrun ọlọ́gbọ́n kanṣoṣo nípa Jesu Kristi títí laelae. Amin.

Rom 16:10-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ kí Apelle, ẹni tí a mọ̀ dájú nínú Kristi. Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Aristobulu. Ẹ kí Herodioni, ìbátan mi. Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Narkissu tí wọ́n wá nínú Olúwa. Ẹ kí Trifena àti Trifosa, àwọn obìnrin tí wọ́n ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa. Ẹ kí Persi ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, obìnrin mìíràn tí ó ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa. Ẹ kí Rufusi, ẹni tí a yàn nínú Olúwa, àti ìyá rẹ̀ àti ẹni tí ó ti jẹ́ ìyá fún èmi náà pẹ̀lú. Ẹ kí Asinkritu, Flegoni, Herma, Patroba, Hermesi àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ó wà pẹ̀lú wọn. Ẹ kí Filologu, àti Julia, Nereu, àti arábìnrin rẹ̀, àti Olimpa, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà pẹ̀lú wọn. Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín. Gbogbo ìjọ Kristi kí yín. Èmí rọ̀ yín, ara, kí ẹ máa sọ àwọn tí ń fa ìyapa, àti àwọn tí ń mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá sí ọ̀nà yín, èyí tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ̀yin kọ́. Ẹ yà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. Nítorí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sin Kristi Olúwa wa, bí kò ṣe ikùn ara wọn. Nípa ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ dídùndídùn ni wọ́n fi ń yí àwọn aláìmọ̀kan ní ọkàn padà. Nítorí ìgbọ́ràn yín tànkálẹ̀ dé ibi gbogbo, nítorí náà mo ní ayọ̀ lórí yín; ṣùgbọ́n èmi fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n sí ohun tí ó ṣe rere, kí ẹ sì ṣe òpè sí ohun tí í ṣe búburú. Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Satani mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín. Timotiu alábáṣiṣẹ́ mi, àti Lukiu, àti Jasoni, àti Sosipateru, àwọn ìbátan mi, kí yín. Èmi Tertiu tí ń kọ lẹ́tà yìí, kí yín nínú Olúwa. Gaiu, ẹni tí èmi àti gbogbo ìjọ gbádùn ìtọ́jú wa tí ó ṣe náà fi ìkíni ránṣẹ́. Erastu, ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ìṣúra ìlú, àti arákùnrin wa Kuartu fi ìkíni wọn ránṣẹ́. Ǹjẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín. Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìhìnrere mi àti ìpolongo Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìṣípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé, ṣùgbọ́n, nísinsin yìí, a ti fihàn nípa ìwé mímọ́ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbọ́ràn tí ó wá láti inú ìgbàgbọ́; kí ògo wà fún Ọlọ́run, Ẹnìkan ṣoṣo tí ọgbọ́n í ṣe tirẹ̀ nípa Jesu Kristi títí láé! Àmín.