Romu 14:5-8

Romu 14:5-8 YCB

Ẹnìkan bu ọlá fún ọjọ́ kan ju òmíràn; ẹlòmíràn bu ọlá fún ọjọ́ gbogbo bákan náà. Kí olúkúlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú ní inú ara rẹ̀. Ẹni tí ó bá ya ọjọ́ kan sí ọ̀tọ̀, ó ń yà á sọ́tọ̀ fún Olúwa. Ẹni tí ó ń jẹ ẹran, ó ń jẹ ẹran fún Olúwa, nítorí pé òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; ẹni tí kò bá sì jẹ ẹran, kò jẹ ẹran fún Olúwa, òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè fún ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó kú fún ara rẹ̀. Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa; bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa. Nítorí náà, bí a wà láààyè, tàbí bí a kú, ti Olúwa ni àwa i ṣe.