Rom 14:5-8
Rom 14:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹlomĩ mbuyìn fun ọjọ kan jù omiran lọ: ẹlomĩ mbuyìn fun ọjọ gbogbo bakanna. Ki olukuluku ki o da ara rẹ̀ loju ni inu ara rẹ̀. Ẹniti o ba nkiyesi ọjọ, o nkiyesi i fun Oluwa; ẹniti kò ba si kiyesi ọjọ, fun Oluwa ni kò kiyesi i. Ẹniti njẹun, o njẹun fun Oluwa, nitori o ndupẹ lọwọ Ọlọrun; ẹniti kò ba si jẹun, fun Oluwa ni kò jẹun, o si ndupẹ lọwọ Ọlọrun. Nitori kò si ẹnikan ninu wa ti o wà lãye fun ara rẹ̀, kò si si ẹniti o nkú fun ara rẹ̀. Nitori bi a ba wà lãye, awa wà lãye fun Oluwa; bi a ba si kú, awa kú fun Oluwa: nitorina bi a wà lãye, tabi bi a kú ni, ti Oluwa li awa iṣe.
Rom 14:5-8 Yoruba Bible (YCE)
Ẹnìkan ka ọjọ́ kan sí ọjọ́ pataki ju ọjọ́ mìíràn lọ, ẹlòmíràn ka gbogbo ọjọ́ sí bákan náà. Ẹ jẹ́ kí olukuluku pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ nípa irú ọ̀ràn báwọ̀nyí. Ẹni tí ó gbé ọjọ́ kan ga ju ọjọ́ mìíràn lọ, ti Oluwa ni ó ń rò. Ẹni tí ó ń jẹ oríṣìíríṣìí oúnjẹ, ó ń jẹ ẹ́ nítorí Oluwa. Ọpẹ́ ni ó ń fi fún Ọlọrun. Ẹni tí kò jẹ, kò jẹ ẹ́ nítorí Oluwa, ọpẹ́ ni òun náà ń fi fún Ọlọrun. Kò sí ẹni tí ó lè wà láàyè fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni, kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, òun nìkan ni ikú òun kàn. Bí a bá wà láàyè, Oluwa ni a wà láàyè fún. Bí a bá sì kú, Oluwa ni a kú fún. Nítorí náà, ààyè wa ni o, òkú wa ni o, ti Oluwa ni wá.
Rom 14:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹnìkan bu ọlá fún ọjọ́ kan ju òmíràn; ẹlòmíràn bu ọlá fún ọjọ́ gbogbo bákan náà. Kí olúkúlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú ní inú ara rẹ̀. Ẹni tí ó bá ya ọjọ́ kan sí ọ̀tọ̀, ó ń yà á sọ́tọ̀ fún Olúwa. Ẹni tí ó ń jẹ ẹran, ó ń jẹ ẹran fún Olúwa, nítorí pé òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; ẹni tí kò bá sì jẹ ẹran, kò jẹ ẹran fún Olúwa, òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè fún ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó kú fún ara rẹ̀. Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa; bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa. Nítorí náà, bí a wà láààyè, tàbí bí a kú, ti Olúwa ni àwa i ṣe.