Ìfihàn 6:7-11
Ìfihàn 6:7-11 BMYO
Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kan wí pé, “Wá wò ó!” Mo sì wò ó, kíyèsi, ẹṣin ràndànràndàn kan, orúkọ ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni ikú, àti ipò òkú sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. A sì fi agbára fún wọn lórí ìdámẹ́rin ayé, láti fi idà, àti ebi, àti ikú, àti ẹranko lu orí ilẹ̀ ayé pa. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìímú, Wọ́n kígbe ní ohùn rara, wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa Olódùmarè, ẹni mímọ́ àti olóòtítọ́ ìwọ kì yóò ṣe ìdájọ́ kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa mọ́ lára àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé?” A sì fi aṣọ funfun fún gbogbo wọn; a sì wí fún wọn pé, kí wọn kí ó sinmi fún ìgbà díẹ̀ ná, títí iye àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti arákùnrin wọn tí a o pa bí wọn, yóò fi dé.

