Ifi 6:7-11
Ifi 6:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o si ṣí èdidi kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye kẹrin nwipe, Wá wò o. Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin rọndọnrọndọn kan: orukọ ẹniti o joko lori rẹ̀ ni Ikú, ati Ipò-okú si tọ̀ ọ lẹhin. A si fi agbara fun wọn lori idamẹrin aiye, lati fi idà, ati ebi, ati ikú, ati ẹranko ori ilẹ aiye pa. Nigbati o si ṣí èdidi karun, mo ri labẹ pẹpẹ, ọkàn awọn ti a ti pa nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati nitori ẹrí ti nwọn dìmu: Nwọn kigbe li ohùn rara, wipe, Yio ti pẹ to, Oluwa, Ẹni-Mimọ́ ati olõtọ, iwọ ki yio ṣe idajọ ki o si gbẹsan ẹ̀jẹ wa mọ́ lara awọn ti ngbé ori ilẹ aiye? A si fi aṣọ funfun fun gbogbo wọn; a si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o simi di ìgba diẹ na, titi iye awọn iranṣẹ ẹlẹgbẹ ati arakunrin wọn ti a o pa bi wọn, yio fi pé.
Ifi 6:7-11 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó tú èdìdì kẹrin, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹrin ní, “Wá!” Mo wá rí ẹṣin kan tí àwọ̀ rẹ̀ rí bíi ti ewéko tútù. Orúkọ ẹni tí ó gùn ún ni Ikú. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Ipò-òkú. A fún wọn ní àṣẹ láti fi idà ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn ati ẹranko burúkú pa idamẹrin ayé. Nígbà tí ó tú èdìdì karun-un, ní abẹ́ pẹpẹ ìrúbọ, mo rí ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́. Àwọn náà kígbe pé, “Oluwa mímọ́ ati olóòótọ́, nígbà wo ni ìwọ yóo ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí ìwọ yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa lára wọn?” A wá fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ funfun. A sọ fún wọn pé kí wọ́n sinmi díẹ̀ sí i títí iye àwọn iranṣẹ ẹlẹgbẹ́ wọn ati àwọn arakunrin wọn yóo fi pé, àwọn tí wọn yóo pa láìpẹ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pa àwọn ti iṣaaju.
Ifi 6:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kan wí pé, Wá wò ó. Mo sì wò ó, kíyèsi, ẹṣin ràndànràndàn kan: orúkọ ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni ikú, àti ipò òkú sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. A sì fi agbára fún wọn lórí ìdámẹ́rin ayé, láti fi idà, àti ebi, àti ikú, àti ẹranko lu orí ilẹ̀ ayé pa. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìímú: Wọ́n kígbe ní ohùn rara, wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa Olódùmarè, ẹni mímọ́ àti olóòtítọ́ ìwọ kì yóò ṣe ìdájọ́ kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa mọ́ lára àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé?” A sì fi aṣọ funfun fún gbogbo wọn; a sì wí fún wọn pé, kí wọn kí ó sinmi fún ìgbà díẹ̀ ná, títí iye àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti arákùnrin wọn tí a o pa bí wọn, yóò fi dé.