Ìfihàn 1:8-20

Ìfihàn 1:8-20 YCB

“Èmi ni Alfa àti Omega,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, alágbára.” Èmi, Johanu, arákùnrin yín àti alábápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jesu, wà ní erékúṣù tí a ń pè ní Patmo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jesu Kristi. Mo wà nínú Ẹ̀mí ní ọjọ́ Olúwa, mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ́yìn mi, bí ìró ìpè, Ó ń wí pé, “Kọ́ ìwé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje; sí Efesu, àti sí Smirna, àti sí Pargamu, àti sí Tiatira, àti sí Sardi, àti sí Filadelfia, àti sí Laodikea.” Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo yípadà, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà méje; àti láàrín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnìkan tí ó dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí a wọ̀ ní aṣọ tí ó kanlẹ̀ dé ẹsẹ̀, tí a sì fi àmùrè wúrà dì ní ẹ̀gbẹ́. Orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó funfun bí yìnyín; ojú rẹ̀ sì dàbí, ọwọ́ iná; Ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀. Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde: Ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn. Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn. Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsi i, èmi sì ń bẹ láààyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò òkú lọ́wọ́. “Kọ̀wé nítorí náà ohun tí ìwọ ti rí, àti ti ohun tí ń bẹ, àti ti ohun tí yóò hù lẹ́yìn èyí; ohun ìjìnlẹ̀ tí ìràwọ̀ méje náà tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ọ̀pá wúrà fìtílà méje náà. Ìràwọ̀ méje ni àwọn angẹli ìjọ méje náà: àti ọ̀pá fìtílà méje náà ní àwọn ìjọ méje.