Ifi 1:8-20

Ifi 1:8-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

Emi ni Alfa ati Omega, ipilẹṣẹ ati opin, li Oluwa wi, ẹniti o mbẹ, ti o ti wà, ti o si mbọ̀wá, Olodumare. Emi Johanu, arakunrin nyin ati alabapin pẹlu nyin ninu wahala ati ijọba ati sũru ti mbẹ ninu Jesu, wà ninu erekuṣu ti a npè ni Patmo, nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati nitori ẹrí Jesu Kristi. Mo wà ninu Ẹmí li ọjọ Oluwa, mo si gbọ́ ohùn nla kan lẹhin mi, bi iró ipè, O nwipe, Emi ni Alfa ati Omega, ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin: ohun ti iwọ ba si ri, kọ ọ sinu iwe, ki o si rán a si awọn ijọ meje; si Efesu, ati si Smirna, ati si Pergamu, ati si Tiatira, ati si Sardi, ati si Filadelfia, ati si Laodikea. Mo si yipada lati wò ohùn ti mba mi sọ̀rọ. Nigbati mo yipada, mo ri ọpá fitila wura meje; Ati lãrin awọn ọpá fitila na, ẹnikan ti o dabi Ọmọ enia, ti a wọ̀ li aṣọ ti o kanlẹ̀ de ẹsẹ, ti a si fi àmure wura dì li ẹgbẹ. Ori rẹ̀ ati irun rẹ̀ funfun bi ẹ̀gbọn owu, o funfun bi sno; oju rẹ̀ si dabi ọwọ́ iná; Ẹsẹ rẹ̀ si dabi idẹ daradara, bi ẹnipe a dà a ninu ileru; ohùn rẹ̀ si dabi iró omi pupọ̀. O si ni irawọ meje li ọwọ́ ọtún rẹ̀; ati lati ẹnu rẹ̀ wá ni idà oloju meji mimú ti jade: oju rẹ̀ si dabi õrùn ti o nfi agbara rẹ̀ ràn. Nigbati mo ri i, mo wolẹ li ẹsẹ rẹ̀ bi ẹniti o kú. O si fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ le mi, o nwi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru; Emi ni ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin: Emi li ẹniti o mbẹ lãye, ti o si ti kú; si kiyesi i, emi si mbẹ lãye si i titi lai, Amin; mo si ní kọkọrọ ikú ati ti ipo-oku. Kọwe ohun gbogbo ti iwọ ti ri, ati ti ohun ti mbẹ, ati ti ohun ti yio hù lẹhin eyi; Ohun ijinlẹ ti irawọ meje na ti iwọ ri li ọwọ́ ọtún mi, ati ọpá wura fitila meje na. Irawọ meje ni awọn angẹli ìjọ meje na: ati ọpá fitila meje na ti iwọ ri ni awọn ijọ meje.

Ifi 1:8-20 Yoruba Bible (YCE)

“Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.” Oluwa Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó ti wà, tí ń bẹ, tí ó sì tún ń bọ̀ wá, Olodumare. Èmi ni Johanu, arakunrin yín ati alábàápín pẹlu yín ninu ìpọ́njú tí ẹni tí ó bá tẹ̀lé Jesu níláti rí, ati ìfaradà tí ó níláti ní. Wọ́n jù mí sí ilẹ̀ kan tí ń jẹ́ Patimosi nítorí mo waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun, mo sì jẹ́rìí pé Jesu ni mo gbàgbọ́. Erékùṣù ni ilẹ̀ Patimosi, ó wà láàrin omi. Nígbà tí ó di Ọjọ́ Oluwa, ni Ẹ̀mí bá gbé mi. Mo gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ́yìn mi bí ìgbà tí fèrè bá ń dún, ó ní, “Kọ ohun tí o bá rí sinu ìwé, kí o fi ranṣẹ sí àwọn ìjọ ní ìlú mejeeje wọnyi: Efesu ati Simana, Pẹgamu ati Tiatira, Sadi ati Filadẹfia ati Laodikia.” Mo bá yipada láti wo ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Bí mo ti yipada, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà meje. Ní ààrin àwọn ọ̀pá fìtílà yìí ni ẹnìkan wà tí ó dàbí eniyan. Ó wọ ẹ̀wù tí ó balẹ̀ dé ilẹ̀. Ó fi ọ̀já wúrà gba àyà. Irun orí rẹ̀ funfun gbòò bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ojú rẹ̀ ń kọ yànràn bí iná. Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí idẹ tí ń dán, tí alágbẹ̀dẹ ń dà ninu iná. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi òkun. Ó mú ìràwọ̀ meje lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. Idà olójú meji tí ó mú yọ jáde lẹ́nu rẹ̀. Ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀ bí oòrùn ọ̀sán gangan. Nígbà tí mo rí i, mo ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó bá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi. Ó ní, “Má bẹ̀rù. Èmi ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn. Èmi ni ẹni tí ó wà láàyè. Mo kú, ṣugbọn mo ti jí, mo sì wà láàyè lae ati laelae. Àwọn kọ́kọ́rọ́ ikú ati ti ipò òkú wà lọ́wọ́ mi. Nítorí náà kọ àwọn ohun tí o rí sílẹ̀, ati àwọn ohun tí ó wà nisinsinyii ati àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la. Àṣírí ìràwọ̀ meje tí o rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ati ti ọ̀pá fìtílà wúrà meje nìyí: ìràwọ̀ meje ni àwọn angẹli ìjọ meje. Ọ̀pá fìtílà meje ni àwọn ìjọ meje.

Ifi 1:8-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Èmi ni Alfa àti Omega,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, alágbára.” Èmi, Johanu, arákùnrin yín àti alábápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jesu, wà ní erékúṣù tí a ń pè ní Patmo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jesu Kristi. Mo wà nínú Ẹ̀mí ní ọjọ́ Olúwa, mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ́yìn mi, bí ìró ìpè, Ó ń wí pé, “Kọ́ ìwé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje; sí Efesu, àti sí Smirna, àti sí Pargamu, àti sí Tiatira, àti sí Sardi, àti sí Filadelfia, àti sí Laodikea.” Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo yípadà, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà méje; àti láàrín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnìkan tí ó dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí a wọ̀ ní aṣọ tí ó kanlẹ̀ dé ẹsẹ̀, tí a sì fi àmùrè wúrà dì ní ẹ̀gbẹ́. Orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó funfun bí yìnyín; ojú rẹ̀ sì dàbí, ọwọ́ iná; Ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀. Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde: Ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn. Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn. Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsi i, èmi sì ń bẹ láààyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò òkú lọ́wọ́. “Kọ̀wé nítorí náà ohun tí ìwọ ti rí, àti ti ohun tí ń bẹ, àti ti ohun tí yóò hù lẹ́yìn èyí; ohun ìjìnlẹ̀ tí ìràwọ̀ méje náà tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ọ̀pá wúrà fìtílà méje náà. Ìràwọ̀ méje ni àwọn angẹli ìjọ méje náà: àti ọ̀pá fìtílà méje náà ní àwọn ìjọ méje.

Ifi 1:8-20

Ifi 1:8-20 YBCVIfi 1:8-20 YBCV