Saamu 86:11-17

Saamu 86:11-17 YCB

Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLúWA, èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ; fún mi ní ọkàn tí kì í yapa, kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ. Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi; ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú. Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run; àti ìjọ àwọn alágbára ń wá ọkàn mi kiri, wọn kò sì fi ọ́ pè. Ṣùgbọ́n ìwọ, OLúWA, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere, Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́. Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi; fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là. Fi ààmì hàn mí fún rere, kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri, kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ OLúWA ni ó ti tù mí nínú.