Saamu 84:1-4

Saamu 84:1-4 YCB

Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó, OLúWA àwọn ọmọ-ogun! Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́ ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá OLúWA àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀ sí Ọlọ́run alààyè. Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé, ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀, níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí: ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀, OLúWA àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi. Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ; wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.