O. Daf 84:1-4

O. Daf 84:1-4 YBCV

AGỌ rẹ wọnni ti li ẹwà to, Oluwa awọn ọmọ-ogun! Ọkàn mi nfà nitõtọ, o tilẹ pe ongbẹ fun agbala Oluwa: aiya mi ati ara mi nkigbe si Ọlọrun alãye. Nitõtọ, ologoṣẹ ri ile, ati alapandẹdẹ tẹ́ itẹ fun ara rẹ̀, nibiti yio gbe ma pa awọn ọmọ rẹ̀ mọ́ si, ani ni pẹpẹ rẹ wọnni, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọba mi ati Ọlọrun mi. Ibukún ni fun awọn ti ngbe inu ile rẹ: nwọn o ma yìn ọ sibẹ.