Saamu 37:30-40

Saamu 37:30-40 YCB

Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́. Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn; àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀. Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo, Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á. OLúWA kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi, nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀. Dúró de OLúWA, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́. Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà; nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri. Èmi ti rí ènìyàn búburú tí ń hu ìwà ìkà, ó sì fi ara rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá, ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan sí i ó kọjá lọ, sì kíyèsi, kò sì sí mọ́; bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri. Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin; nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà. Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀; ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò. Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA; òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú OLúWA yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n; yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.