O. Daf 37:30-40
O. Daf 37:30-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnu olododo ni ima sọ̀rọ ọgbọ́n, ahọn rẹ̀ a si ma sọ̀rọ idajọ. Ofin Ọlọrun rẹ̀ mbẹ li aiya rẹ̀; ọkan ninu ìrin rẹ̀ kì yio yẹ̀. Ẹni buburu nṣọ olododo, o si nwá ọ̀na lati pa a. Oluwa kì yio fi i le e lọwọ, kì yio si da a lẹbi, nigbati a ba nṣe idajọ rẹ̀. Duro de Oluwa, ki o si ma pa ọ̀na rẹ̀ mọ́, yio si gbé ọ leke lati jogun aiye: nigbati a ba ké awọn enia buburu kuro, iwọ o ri i. Emi ti nri enia buburu, ẹni ìwa-ika, o si fi ara rẹ̀ gbilẹ bi igi tutu nla. Ṣugbọn o kọja lọ, si kiyesi i, kò sí mọ: lõtọ emi wá a kiri, ṣugbọn a kò le ri i. Ma kiyesi ẹni pipé, ki o si ma wò ẹni diduro ṣinṣin: nitori alafia li opin ọkunrin na. Ṣugbọn awọn alarekọja li a o parun pọ̀; iran awọn enia buburu li a o ké kuro. Ṣugbọn lati ọwọ Oluwa wá ni igbala awọn olododo; on li àbo wọn ni igba ipọnju. Oluwa yio si ràn wọn lọwọ, yio si gbà wọn, yio si gbà wọn lọwọ enia buburu, yio si gbà wọn la, nitoriti nwọn gbẹkẹle e.
O. Daf 37:30-40 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa jáde lẹ́nu ẹni rere, a sì máa sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́. Òfin Ọlọrun rẹ̀ wà ní ọkàn rẹ̀; ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í yà kúrò níbẹ̀. Eniyan burúkú ń ṣọ́ olódodo, ó ń wá ọ̀nà ati pa á. OLUWA kò ní fi olódodo lé e lọ́wọ́, tabi kí ó jẹ́ kí á dá olódodo lẹ́bi ní ilé ẹjọ́. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, sì máa tọ ọ̀nà rẹ̀, yóo gbé ọ ga, kí o lè jogún ilẹ̀ náà; nígbà tí a bá pa àwọn eniyan burúkú run, o óo fojú rẹ rí i. Mo ti rí eniyan burúkú tí ń halẹ̀ mọ́ni, tí ó ga bí igi kedari ti Lẹbanoni. Ṣugbọn nígbà tí mo tún gba ibẹ̀ kọjá, mo wò ó, kò sí níbẹ̀ mọ́; mo wá a, ṣugbọn n kò rí i. Ṣe akiyesi ẹni pípé; sì wo olódodo dáradára, nítorí pé ìgbẹ̀yìn ẹni tí ń wá alaafia yóo dára. Ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo parun patapata, a óo sì run ọmọ àwọn eniyan burúkú. Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìgbàlà àwọn olódodo ti ń wá; òun ni alátìlẹ́yìn wọn ní àkókò ìṣòro. OLUWA a máa ràn wọ́n lọ́wọ́, a sì máa gbà wọ́n; a máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú, a sì máa gbà wọ́n là, nítorí pé òun ni wọ́n sá di.
O. Daf 37:30-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́. Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn; àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀. Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo, Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á. OLúWA kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi, nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀. Dúró de OLúWA, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́. Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà; nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri. Èmi ti rí ènìyàn búburú tí ń hu ìwà ìkà, ó sì fi ara rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá, ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan sí i ó kọjá lọ, sì kíyèsi, kò sì sí mọ́; bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri. Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin; nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà. Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀; ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò. Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA; òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú OLúWA yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n; yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.