ORIN DAFIDI 37:30-40

ORIN DAFIDI 37:30-40 YCE

Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa jáde lẹ́nu ẹni rere, a sì máa sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́. Òfin Ọlọrun rẹ̀ wà ní ọkàn rẹ̀; ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í yà kúrò níbẹ̀. Eniyan burúkú ń ṣọ́ olódodo, ó ń wá ọ̀nà ati pa á. OLUWA kò ní fi olódodo lé e lọ́wọ́, tabi kí ó jẹ́ kí á dá olódodo lẹ́bi ní ilé ẹjọ́. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, sì máa tọ ọ̀nà rẹ̀, yóo gbé ọ ga, kí o lè jogún ilẹ̀ náà; nígbà tí a bá pa àwọn eniyan burúkú run, o óo fojú rẹ rí i. Mo ti rí eniyan burúkú tí ń halẹ̀ mọ́ni, tí ó ga bí igi kedari ti Lẹbanoni. Ṣugbọn nígbà tí mo tún gba ibẹ̀ kọjá, mo wò ó, kò sí níbẹ̀ mọ́; mo wá a, ṣugbọn n kò rí i. Ṣe akiyesi ẹni pípé; sì wo olódodo dáradára, nítorí pé ìgbẹ̀yìn ẹni tí ń wá alaafia yóo dára. Ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo parun patapata, a óo sì run ọmọ àwọn eniyan burúkú. Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìgbàlà àwọn olódodo ti ń wá; òun ni alátìlẹ́yìn wọn ní àkókò ìṣòro. OLUWA a máa ràn wọ́n lọ́wọ́, a sì máa gbà wọ́n; a máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú, a sì máa gbà wọ́n là, nítorí pé òun ni wọ́n sá di.