Saamu 37:12-29

Saamu 37:12-29 YCB

Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́, wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn; ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú, nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀. Ènìyàn búburú fa idà yọ, wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn, láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀, láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin. Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ, àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́. Ohun díẹ̀ tí olódodo ní, sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú; nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n OLúWA gbé olódodo sókè. OLúWA mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin, àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé; Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi, àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé. Àwọn ọ̀tá OLúWA yóò dàbí ẹwà oko tútù; wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò. Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà, ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni; Nítorí àwọn tí OLúWA bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà, àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò. Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA wá, o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀; Bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá, nítorí tí OLúWA di ọwọ́ rẹ̀ mú. Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà; síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ. Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni; a sì máa bùsi i fún ni. Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere; nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé. Nítorí pé OLúWA fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́, kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò. Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà, yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.