ORIN DAFIDI 37:12-29

ORIN DAFIDI 37:12-29 YCE

Eniyan burúkú dìtẹ̀ mọ́ olódodo; ó sì ń wò ó bíi kíkú bíi yíyè. Ṣugbọn OLUWA ń fi eniyan burúkú rẹ́rìn-ín, nítorí ó mọ̀ pé ọjọ́ ìparun rẹ̀ ń bọ̀. Àwọn eniyan burúkú fa idà yọ, wọ́n sì kẹ́ ọfà wọn láti gba ẹ̀mí talaka ati aláìní, láti pa àwọn tí ń rìn lọ́nà ẹ̀tọ́. Ṣugbọn idà wọn ni o óo fi pa wọ́n, ọrun wọn yóo sì dá. Nǹkan díẹ̀ tí olódodo ní dára ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú. Nítorí OLUWA yóo ṣẹ́ apá eniyan burúkú, ṣugbọn yóo gbé olódodo ró. OLUWA a máa tọ́jú àwọn aláìlẹ́bi; ilẹ̀ ìní wọn yóo jẹ́ tiwọn títí lae. Ojú kò ní tì wọ́n nígbà tí àjálù bá dé; bí ìyàn tilẹ̀ mú, wọn óo jẹ, wọn óo yó. Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé; àwọn ọ̀tá OLUWA yóo pòórá bí ẹwà ewéko wọn óo parẹ́ bí èéfín tí í parẹ́. Bí eniyan burúkú bá yá owó, kò ní san; ṣugbọn ẹni rere ní ojú àánú, ó sì lawọ́. Nítorí pé àwọn tí Ọlọrun bá bukun ni yóo jogún ilẹ̀ náà, ṣugbọn àwọn tí ó bá fi gégùn-ún yóo parun. OLUWA níí darí ìgbésẹ̀ ẹni; a sì máa fi ẹsẹ̀ ẹni tí inú rẹ̀ bá dùn sí múlẹ̀. Bí ó tilẹ̀ ṣubú, kò ní lulẹ̀ lógèdèǹgbé, nítorí OLUWA yóo gbé e ró. Mo ti jẹ́ ọmọde rí; mo sì ti dàgbà: n kò tíì ri kí á kọ olódodo sílẹ̀, tabi kí ọmọ rẹ̀ máa tọrọ jẹ. Olódodo ní ojú àánú, a sì máa yáni ní nǹkan, ayọ̀ ń bẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ yẹra fún ibi; ẹ sì máa ṣe rere; kí ẹ lè wà ní ààyè yín títí lae. Nítorí OLUWA fẹ́ràn ẹ̀tọ́; kò ní kọ àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sílẹ̀. Yóo máa ṣọ́ wọn títí lae, ṣugbọn a óo pa àwọn ọmọ eniyan burúkú run. Àwọn ẹni rere ni yóo jogún ilẹ̀ náà; wọn óo sì máa gbé orí rẹ̀ títí lae.