O. Daf 37:12-29

O. Daf 37:12-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

Enia buburu di rikiṣi si olõtọ, o si pa ehin rẹ̀ keke si i lara. Oluwa yio rẹrin rẹ̀; nitori ti o ri pe, ọjọ rẹ̀ mbọ̀. Awọn enia buburu ti fà idà yọ, nwọn si ti fà ọrun wọn le, lati sọ talaka ati alaini kalẹ, ati lati pa iru awọn ti nrin li ọ̀na titọ. Idà wọn yio wọ̀ aiya wọn lọ, ọrun wọn yio si ṣẹ́. Ohun diẹ ti olododo ni sanju ọrọ̀ ọ̀pọ enia buburu. Nitoriti a o ṣẹ́ apa awọn enia buburu: ṣugbọn Oluwa di olododo mu. Oluwa mọ̀ ọjọ ẹni iduro-ṣinṣin: ati ilẹ-ini wọn yio wà lailai. Oju kì yio tì wọn ni igba ibi: ati li ọjọ ìyan a o tẹ́ wọn lọrun. Ṣugbọn awọn enia buburu yio ṣegbe, awọn ọta Oluwa yio dabi ẹwà oko-tutu: nwọn o run; ẹ̃fin ni nwọn o run si. Awọn enia buburu wín, nwọn kò si pada san: ṣugbọn olododo a ma ṣãnu, a si ma fi funni. Nitoriti awọn ẹni-ibukún rẹ̀ ni yio jogun aiye; awọn ẹni-egún rẹ̀ li a o ke kuro. A ṣe ìlana ẹsẹ enia lati ọwọ Oluwa wá: o si ṣe inu didùn si ọ̀na rẹ̀. Bi o tilẹ ṣubu, a kì yio ta a nù kuro patapata; nitoriti Oluwa di ọwọ rẹ̀ mu. Emi ti wà li ewe, emi si dagba; emi kò ti iri ki a kọ̀ olododo silẹ, tabi ki iru-ọmọ rẹ̀ ki o ma ṣagbe onjẹ. Alãnu li on nigbagbogbo, a ma wín ni: a si ma busi i fun iru-ọmọ rẹ̀. Kuro ninu ibi ki o si ma ṣe rere; ki o si ma joko lailai. Nitoriti Oluwa fẹ idajọ, kò si kọ̀ awọn enia mimọ́ rẹ̀ silẹ; a si pa wọn mọ́ lailai: ṣugbọn iru-ọmọ awọn enia buburu li a o ke kuro. Olododo ni yio jogun aiye, yio si ma gbe inu rẹ̀ lailai.

O. Daf 37:12-29 Yoruba Bible (YCE)

Eniyan burúkú dìtẹ̀ mọ́ olódodo; ó sì ń wò ó bíi kíkú bíi yíyè. Ṣugbọn OLUWA ń fi eniyan burúkú rẹ́rìn-ín, nítorí ó mọ̀ pé ọjọ́ ìparun rẹ̀ ń bọ̀. Àwọn eniyan burúkú fa idà yọ, wọ́n sì kẹ́ ọfà wọn láti gba ẹ̀mí talaka ati aláìní, láti pa àwọn tí ń rìn lọ́nà ẹ̀tọ́. Ṣugbọn idà wọn ni o óo fi pa wọ́n, ọrun wọn yóo sì dá. Nǹkan díẹ̀ tí olódodo ní dára ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú. Nítorí OLUWA yóo ṣẹ́ apá eniyan burúkú, ṣugbọn yóo gbé olódodo ró. OLUWA a máa tọ́jú àwọn aláìlẹ́bi; ilẹ̀ ìní wọn yóo jẹ́ tiwọn títí lae. Ojú kò ní tì wọ́n nígbà tí àjálù bá dé; bí ìyàn tilẹ̀ mú, wọn óo jẹ, wọn óo yó. Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé; àwọn ọ̀tá OLUWA yóo pòórá bí ẹwà ewéko wọn óo parẹ́ bí èéfín tí í parẹ́. Bí eniyan burúkú bá yá owó, kò ní san; ṣugbọn ẹni rere ní ojú àánú, ó sì lawọ́. Nítorí pé àwọn tí Ọlọrun bá bukun ni yóo jogún ilẹ̀ náà, ṣugbọn àwọn tí ó bá fi gégùn-ún yóo parun. OLUWA níí darí ìgbésẹ̀ ẹni; a sì máa fi ẹsẹ̀ ẹni tí inú rẹ̀ bá dùn sí múlẹ̀. Bí ó tilẹ̀ ṣubú, kò ní lulẹ̀ lógèdèǹgbé, nítorí OLUWA yóo gbé e ró. Mo ti jẹ́ ọmọde rí; mo sì ti dàgbà: n kò tíì ri kí á kọ olódodo sílẹ̀, tabi kí ọmọ rẹ̀ máa tọrọ jẹ. Olódodo ní ojú àánú, a sì máa yáni ní nǹkan, ayọ̀ ń bẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ yẹra fún ibi; ẹ sì máa ṣe rere; kí ẹ lè wà ní ààyè yín títí lae. Nítorí OLUWA fẹ́ràn ẹ̀tọ́; kò ní kọ àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sílẹ̀. Yóo máa ṣọ́ wọn títí lae, ṣugbọn a óo pa àwọn ọmọ eniyan burúkú run. Àwọn ẹni rere ni yóo jogún ilẹ̀ náà; wọn óo sì máa gbé orí rẹ̀ títí lae.

O. Daf 37:12-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́, wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn; ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú, nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀. Ènìyàn búburú fa idà yọ, wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn, láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀, láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin. Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ, àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́. Ohun díẹ̀ tí olódodo ní, sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú; nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n OLúWA gbé olódodo sókè. OLúWA mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin, àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé; Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi, àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé. Àwọn ọ̀tá OLúWA yóò dàbí ẹwà oko tútù; wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò. Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà, ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni; Nítorí àwọn tí OLúWA bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà, àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò. Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA wá, o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀; Bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá, nítorí tí OLúWA di ọwọ́ rẹ̀ mú. Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà; síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ. Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni; a sì máa bùsi i fún ni. Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere; nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé. Nítorí pé OLúWA fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́, kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò. Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà, yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.