Saamu 31:19-24

Saamu 31:19-24 YCB

Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó, èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn. Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn; ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu kúrò nínú ìjà ahọ́n. Olùbùkún ni OLúWA, nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn, nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká. Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi, “A gé mi kúrò ní ojú rẹ!” Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́. Ẹ fẹ́ OLúWA, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́! OLúWA pa olódodo mọ́, ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de OLúWA.