O. Daf 31:19-24
O. Daf 31:19-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó, èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn. Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn; ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu kúrò nínú ìjà ahọ́n. Olùbùkún ni OLúWA, nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn, nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká. Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi, “A gé mi kúrò ní ojú rẹ!” Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́. Ẹ fẹ́ OLúWA, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́! OLúWA pa olódodo mọ́, ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de OLúWA.
O. Daf 31:19-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ore rẹ ti tobi to, ti iwọ fi ṣura dè awọn ti o bẹru rẹ: ore ti iwọ ti ṣe fun awọn ti o gbẹkẹle ọ niwaju awọn ọmọ enia! Iwọ o pa wọn mọ́ ni ibi ìkọkọ iwaju rẹ kuro ninu idimọlu awọn enia; iwọ o pa wọn mọ́ ni ìkọkọ ninu agọ kan kuro ninu ija ahọn. Olubukún ni Oluwa; nitori ti o ti fi iṣeun-ifẹ iyanu rẹ̀ hàn mi ni ilu olodi. Nitori ti mo ti wi ni ikanju mi pe, A ke mi kuro niwaju rẹ: ṣugbọn iwọ gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi nigbati mo kepè ọ. Ẹ fẹ Oluwa, gbogbo ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́: Oluwa npa onigbagbọ́ mọ́, o si san a li ọ̀pọlọpọ fun ẹniti nṣe igberaga. Ẹ tujuka, yio si mu nyin li aiya le, gbogbo ẹnyin ti o ni ireti niti Oluwa.
O. Daf 31:19-24 Yoruba Bible (YCE)
Háà! Ohun rere mà pọ̀ lọ́wọ́ rẹ o tí o ti sọ lọ́jọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, tí o sì ti pèsè ní ìṣojú àwọn ọmọ eniyan, fún àwọn tí ó sá di ọ́. O fi ìyẹ́ apá rẹ ṣíji bò wọ́n; o pa wọ́n mọ́ kúrò ninu rìkíṣí àwọn eniyan; o sì pa wọ́n mọ́ lábẹ́ ààbò rẹ, kúrò lọ́wọ́ ẹnu àwọn ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́. Ẹni ìyìn ni OLUWA, nítorí pé, lọ́nà ìyanu, ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn mí, nígbà tí ilẹ̀ ká mi mọ́. Ẹ̀rù bà mí, mo sì sọ pé, “A lé mi jìnnà kúrò ní iwájú rẹ.” Ṣugbọn o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́. Ẹ fẹ́ràn OLUWA, gbogbo ẹ̀yin olódodo, OLUWA a máa ṣọ́ àwọn olóòótọ́, a sì máa san àlékún ẹ̀san fún àwọn agbéraga. Ẹ múra gírí, kí ẹ sì mọ́kàn le, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.