Saamu 31:1-4

Saamu 31:1-4 YCB

Nínú rẹ̀, OLúWA ni mo ti rí ààbò; Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí; gbà mí nínú òdodo rẹ. Tẹ́ etí rẹ sí mi, gbà mí kíákíá; jẹ́ àpáta ààbò mi, jẹ́ odi alágbára láti gbà mí. Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi, nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi. Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi, nítorí ìwọ ni ìsádi mi.