O. Daf 31:1-4

O. Daf 31:1-4 YBCV

OLUWA, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: máṣe jẹ ki oju ki o tì mi: gbà mi ninu ododo rẹ. Dẹ eti rẹ silẹ si mi: gbà mi nisisiyi: iwọ ma ṣe apata agbara mi, ile-ãbò lati gba mi si. Nitori iwọ li apata mi ati odi mi: nitorina nitori orukọ rẹ ma ṣe itọ́ mi, ki o si ma ṣe amọ̀na mi. Yọ mi jade ninu àwọn ti nwọn nà silẹ fun mi ni ìkọkọ: nitori iwọ li ãbo mi.