Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ OLúWA, òhun ni èmi yóò máa wá kiri: kí èmi kí ó le wà ní ilé OLúWA ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà OLúWA, kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀. Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀; níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́; yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta. Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká; èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀; èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí OLúWA. Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Háà! OLúWA, ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn; “Wá,” ọkàn mi wí pé, “wá ojú u rẹ̀.” Ojú rẹ, OLúWA, ni èmí ń wá. Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi, má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì; ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi, Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí, háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.
Kà Saamu 27
Feti si Saamu 27
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Saamu 27:4-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò